Please contact us through the qtox tool
Download qtox https://github.com/qTox/qTox/blob/master/README.md#qtox
If you can't contact us, please contact some data recovery company(suggest taobao.com), may they can contact to us.
Add our TOX ID and send an encrypted file and 'Sorry-ID' for testing decryption.
Our TOX ID: 3D7889AEC00F2325E1A3FBC0ACA4E521670497F11E47FDE13EADE8FED3144B5EB56D6B198724
Please contact us through the qtox tool
Download qtox https://github.com/qTox/qTox/blob/master/README.md#qtox
If you can't contact us, please contact some data recovery company(suggest taobao.com), may they can contact to us.
Add our TOX ID and send an encrypted file and 'Sorry-ID' for testing decryption.
Our TOX ID: 3D7889AEC00F2325E1A3FBC0ACA4E521670497F11E47FDE13EADE8FED3144B5EB56D6B198724
Itan Keresimesi yi ko kan bere ni ile Isreali bi egberun odun meji seyin. Wiwa Olorun si aye ni aworan eniyan je, afihan oun ti Olorun ti se eto re sile ni Orun ki a to da aye rara (1 Peteru1:18-20) Niwonbi….. enyin ti mo pe, “a ko fi ohun ti idibaje ra yin pada, bi fadaka tabi wura, kuro ninu iwa asan nyin, ti enyin ti jogun lati odo awon baba nyin; Bi ko se eje iyebiye, bi ti odo-aguntan ti ko li abuku, ti ko si li abawon, ani eje Kristi: Eniti a ti mo tele nitooto saaju ipilese aye, sugbon ti a fihan ni igba ikehin wonyi nitori nyin”. Eyi tumo si wipe bibi, iku ati ajinde Jesu Kristi ti sele ni Orun ki a to da aye. Oun ti o si sele ni Bethlehemu je aworan tabi afihan fun araye oun ti o sele ni Orun.
O le ma beere idi ti o fi se pataki fun Jesu lati wa si aye? Ranti Adamu ati Efa ninu ogba Edeni, ibi ti o kun fun opo yanturu ati ajosepo to gun rege laarin Olorun ati eniyan. Ajosepo to gun rege yi lo baje nigbati Adamu ati Efa se si Olorun ti a si le won kuro ninu ogba Edeni. Ese Adamu yi lo ni ipa lori gbogbo awon omo eniyan. (Romu 3:23) “Gbogbo eniyan li o sa ti se, ti nwon si kuna ogo Olorun” Ese yi lo wa fi ogbun nla si arin Olorun ati eniyan eyiti a gbodo di ki ajosepo miran to tun le wa laarin Olorun ati Eniyan. Idi eleyi lo mu ki Olorun ran omo Re wa si aye nigba Keresimesi (John 3:16) “Nitori Olorun fe araye tobee ge ti o fi Omo bibi re kan soso funni, ki enikeni ti o ba gba gbo ma ba segbe, sugbon ki o le ni iye ainipekun”.
Olorun ni lati ran Omo Re ni aworan eniyan eleran ara (Johannu 1:14 )”Oro naa si di ara , oun si n ba wa gbe, t’awa si n wo ogo re, ogo bi ti omo bibi kansoso lati odo Baba wa, t’o kun fun oore – ofe ati otito.”; (Filippi 2:8) nitoripe ona kanna niyi nipase eyiti eniyan le fi ni oye oun ti Olorun n so. Fun apeere, bawo ni eniyan se le kilo fun opolopo kokoro eera wipe ewu agbara tabi ina ti o le pa won run fe sele si won. Bi o ba pariwo, awon eera ko le gbo. Ona kan na ti o fi le je ki won mo nipa ewu ti o n bo yi ni ki oun na papa di eera. Oun naa gan ti Olorun se ni eyi (Heb1:1-2) “Olorun, ni igba pupo ati li oniruuru ona, ti o ti ipa awon woli ba awon baba soro nigbaani, ni ikehin ojo wonyi o ti ipase omo re ba wa soro eniti o fi se ajogun ohun gbogbo nipase eniti o da awon aye pelu”;
Oun ti Jesu wa se laye ni lati se ilaja laarin Olorun ati omo eniyan (2korinti 5:19) “Eyini ni pe, Olorun wa ninu Kristi, O n ba araye laja sodo ara re, ko si ka irekoja won si won lorun O si ti fi oro ilaja le wa lowo!!”. Nje o gbo iroyin ayo ati iyanu yi? Olorun ko ka ese re si o lorun nitoripe o ran omo Re si o ni asiko Keresimesi lati gba iku re ku. (1Peteru 3:18) ” Nitori eyi, a dari gbogbo ese ti a ti se ji wa “Je ki eniyan buburu ko ona re sile, ki elese si ko ironu re sile, si je ki o yi pada si OLUWA, oun o si saanu fun, ati si olorun wa, yio si fi ji li opolopo” (Isa. 55:7)”. Eyi ni itan iyanu ti Keresimesi.
Ore, ibeere pataki kan ti Olorun yo bere lowo eni kokan wa nigba ti a ba de orun ni eyi “ki ni o se nipa Jesu Kristi, ebun iyanu ti Keresimesi”. Nigbati a fe bi Jesu ni Bethlehemu, aye ko si fun Josefu ati Maria ni ile ero. Eyi lo mu ki a bi Jesu ni ibuje eran. Ni o le egberun odun meji leyin eleyi, ogooro eniyan ni ko ni aye fun Jesu ninu aye won, bi o tile je pelu idunnu ni won fi n se ajoyo Keresimesi.
Iwo nko? Se aye wa ninu aye re fun Kristi? Ti o ba gba Jesu bayi, wa lo ayeraye re pelu Olorun ni Orun pelu ayo alailegbe ti o kun fun ogo.
Ti o ba fe gba Jesu Kristi, ebun iyebiye ti Olorun fun wa ni igba Keresimesi sinu aye re, gba adura yi tokantokan”
Jesu Oluwa, mo gbagbo wipe o ku fun ese mi, o si jinde fun idalare mi. Dari ese mi ji mi ki o si fi Eje Re iyebiye ni we mi mo. Wa si inu aye mi ki o si je, Oluwa nibe titi lailai: Jesu o se nitoripe o ti gba mi la.
Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi
Produced and Distributed by
GOSET MEDIA MINISTRIES
]]>“Ko si ohun ti a bo, ti a ki yio si fihan, tabi ti o pamo ti a ki yio mo” (Luku 12:2). Ko si ohun ti eniyan ko le se lati bo ese re mole. O le so ina si odidi ile lati bo ese re mole, pa eniyan tabi pa eniyan lara ki o ma ba si eleri Kankan fun iwa ibaje re ni Iwonba igba ti a ko ba ti ka o mo ibi oran naa. Yoo se oyun lati pa omo ti a ko tii bi lati bo ibasepo ti ko leto mole. Awon eniyan ti won n se eru, ole ipaniyan, ifole ati awon iwa aito miran gba wipe ki awon ku tabi ki won pa eniyan san ju ki asiri won ko tu lo. Gege bi bibeli ti so fun wa, ko si ese naa ti yo wa ni aimo titi.
Igbiyanju omo eniyan lati bo ese re mole mu mi ranti itan kan ti o wa ninu awon iwe adura ojoojumo kan, “Our Daily Bread”. Arakunrin kan wa ti ko ni ise meji ju ise fayawo lo. Ni ojo kan ti o n bo lati ibi ise yi pelu oko oju omi to kun bamu fun awon eru ofin, o ri oko oju omi awon ti o n gbogun ti iwa fayawo ti won n le bo leyin. O pe akiyesi awon ti won nba wa oko oju omi yi si ohun ti o ri won si gbiyanju lati salo mo awon wonyi lowo sugbon laipe won ri wipe won o le bo mo won lowo. Nigba ti ko ri awon agbofinro yi nitosi re mo, o pase wipe ki won da gbogbo awon eru ofin yi sinu okun. Logan naa ni won si se bi o ti wi. Nitori wipe ile ti su, awon gbofinro yi ko ri nkan ti onifayawo yi se. Laipe, ina ti o ntan lati ara oko oju omi awon agbofinro to wa leyin onifayawo yi je ki awon onifayawo ri pe eru ti won da si inu okun ko ri. Eyi ya won lenu pupo. Awon eru wonyi to taara tele awon onifayawo yi, eyi ni o si ran awon agbofinro lowo lati tete se awari won. O gbiyanju lati bo eri iwa odaran re mole sugbon awon eru naa ko lati ri sinu okun. Eleyi ni o si se apejuwe oro Olorun to so wipe “Eniti o bo ese re mole ki yio se rere sugbon enikeni ti o jewo ti o si koo sile yio ri anu”(Iwe Owe 28:13) Nje itan yi ran o leti ese ti o gbiyanju lati bo mole ri? O le dabi eni wipe o ti se aseyori sugbon ni ojo kan “Okun” yio ko lati fi owo so owopo pelu re: oke nla yio ko lati ba o wo lu mole. Ile ko si ni gba lati boo mole bee naa ni yio ma tu sita.
Gbo mi ara, ese ti o ro pe ko si eniti o mo nipa re yen ko bo rara o. Gbo nkan ti bibeli so “Sugbon ohun gbogbo ni o wa ni ihoho ti a si sipaya fun oju re eniti awa ni iba lo”(Heberu 4:13)
O ko le sa pamo fun Olorun. O mo, o si n ri ohun gbogbo ti o nse. Ti o ba ko lati doju ko ese re nisisinyi, laipe lai jinna ese re yio se awari re yio si fi o se esin.
Olorun korira ese, eniyan si gbodo san idiyele gbogbo ese ti o ba se “Nitori iku ni ere ese, sugbon ebun ofe Olorun ni iye ainipekun ninu Kristi Jesu Oluwa wa” (Romu 6: 23)
Ona abayo kanna ti o wa ni nipa Jesu Kristi. Ti o ba jewo ese re fun Olorun bayi, eje Jesu yo we gbogbo awon ese yi danu, eyi si dara ju ki o bo awon ese yi mole lo. Eje Jesu nikan ni o le bo ese eniyan mole patapata. Nitoripe o we ese wonyi nu, o si we o nu mo patapata lai ni eeri kankan. Olorun fe o si ti setan lati gbo ti iwo naa yo ba la enu re ti o si gbadura. Gbadura bayi nisinsiyi
“Jesu Oluwa, mo gbagbo wipe o ku fun ese mi a si ji o dide fun idalare mi. Dari gbogbo ese mi ji mi ki o si fi eje re iyebiye naa we mi. Wa si inu aye mi ki o si je Oluwa lati oni lo. O se Jesu nitori pr o ti gba mi la. Amin.
Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi
Produced and Distributed by
GOSET MEDIA MINISTRIES
]]>
Bawo ni mo se mo eyi? Oro Olorun to je otito ti ko si le puro so lati ye wa yekeyeke ni opolopo igba. Ni igba kan Peteru eniti o je ojo ati oniberu fi igboya so fun awon olori Ju wipe ” Ko si igbala lodo elomiran nitori ko si ORUKO MIRAN labe orun ti a fi fun ni ninu eniyan nipa eyiti a le fi gba wa la”(Ise awon Aposteli 4:12). Peteru n so nipa Oruko Jesu ni ibi ti a ka yi igbala tumo si itusile kuro lowo Satani, ese ati si iye ainipekun. Fun awon eniyan kan ti won si gbagbo ninu eko odi pe opolopo alarina laarin Olorun ati eniyan, amofin Paulu ni oro lati ba yin so ” Nitori Olorun kan ni mbe Onilaja kan pelu laarin Olorun ati eniyan, oun paapa eniyan, ani Kristi Jesu” (1 Timoteu 2 :5). Nitori pataki oro yi Paulu gegun fun enikeni pelu oun funrare ti o ba tun waasu ounkoun to yato si ona igbala yi ” Sugbon bi o se awa ni, tabi angeli kan lati orun wa ni o ba waasu ihinrere miran fun yin ju eyiti eyin ti igba lo je, ki o di eni ifibu” (Galatia 1 :8). Pataki oun ti Paulu nso fun wa ni wipe Jesu ni eni naa ti Olorun ran si omo eniyan (Heberu 1 :2). Jesu funra re so pelu idaniloju wipe ” emi ni ONA otito ati iye. Ko si enikeni ti o le wa sodo Baba bikose nipase mi (Johannu 14 :6). Mo fe ki o se akiyesi wipe Jesu so pe oun ni ONA ki si se okan ninu awon ona.
O tun le beere wipe ki : lo de ti Jesu nikan fi je ona si odo Olorun ?. Je ki a bere pelu itan Adamu ati Efa. Ki won to da ese, ajosepo to dan moran lo wa laarin Olorun ati eniyan. Ese aigboran ti won da lo si ni ipa lori gbogbo omo eniyan di oni yi (Romu 3:23), Iyapa nla ni ese da sile laarin Olorun ati eniyan nitoripe Olorun mimo ko le ni ajosepo pelu omo eniyan to ti di elese, ”Sugbon aisedede yin ni o ya yin kuro lodo Olorun yin, ati ese yin ni o pa oju re mo kuro lodo yin, ti oun ki yio fi gbo” (Isiah 59:2). Ni iwon igba ti o si je wipe lai si itaje sile ko le si idariji (Heberu 9:22). Olorun ni lati ran omo re Jesu lati ku dipo emi ati iwo ” nitori Jesu kristi pelu jiya leekan nitori ese wa, olooto fun awon alaisooto ki o le mu wa de odo Olorun” (1 Peteru 3 :18). Nitoripe Jesu Kristi ti san ijiya fun ese wa nipase eje re iyebiye ni ori igi agbelebu, o si so wa po pelu Olorun ” Eyini ni pe Olorun wa ninu Kristi, o nba araye laja sodo ara re, ko si ka irekoja won si won lorun. (2 Korinti 5 :19) Idi niyi ti oruko Jesu nikan fi je ona si odo Olorun. (Efesu 2 :18, 3 :12).
Ni afikun si eleyi, Jesu ni awon arimuye ti ko ni afiwe ti o si yato gedegede si awon olori tabi oludasile esin miran. Isotele ti wa nipa ibi re lati bi ogoro odun siwaju akoko ibi re. Awon iwa re wa ni ailabawon bakanna lo si tun ni aanu ti ko ni afiwe fun omo eniyan. O gba elese la, o wo alaisan san, o fun awon ti ebi npa ni ounje o si le awon emi esu ati aimo jade ninu awon eniyan. Nitori pe esu, iku ati orun apaadi teriba fun oruko re, eyi fun ni agbara lati le ji awon oku dide. O fi agbara re lori iseda han, o ni ki riru omi okun ko dake je, o tun rin lori omi. Iku ati ajinde re je iyalenu.
Egungun awon oludasile esin miran si wa ninu iboji won di akoko yi. Iboji Jesu wa ni ofo! Titi di oni ipa ti Jesu ni lori gbogbo aye si wa sibe bi o tile je wipe akoko perete ti se odun metale logbon nikan ni o gbe ninu aye yi.
Koda, awon orisun iroyin kan to yato si Bibeli fi idi awon nkan wonyi mule ni pataki julo T.F. Josephus (37-100 AD) ti o ko nipa igbe aye ati ise iranse Jesu. A ri akosile kan naa ni bi egberun odun meji seyin ni Constantinople. Ninu akosile agbelebu Jesu ko si Romu ninu eyiti o ti nse alaye idi re ti o se fi owo si ikanma agbelebu Jesu. Eyi ga, nitori pe eri pe eri po ni opolopo lati fi idi oro Olorun (Bibeli) mule.
Awon oun ti o dara lo ma n sele si eniyan ni igba ti o ba wa si odo Jesu Nitori Jesu nikan ni ONA si odo Olorun. Oun nikan naa ni ona abayo kuro ninu wahala aye re. Oun naa ni Jesu lana, loni ati titi laelae (Heberu 13 :8). Jesu a se ayipada re bi o ti wu ki igbe aye ti o n gbe tele se buru to. Jesu yo fun aye re ni ayo ati idunnu yoo si tun fun o ni ojo ola ti o dara. Gbogbo agbara esu ati awon iranse re bi aje, oso ati beebelo ti di ibaje ni ori re. Jesu yoo fi ibukun re lopolopo fun o yio si ba gbogbo awon aini re pade. Ju gbogbo re lo, yio mu o lo si orun ti o kun fun alafia, ayo ati itunu.
Oluka oro mi yi, akoko niyi fun o lati se ipinu Pilatu eni ti o fi owo si ikanmo agbelebu Kristi beere ibeere pataki kan lowo awon Olufisun Jesu ” Kili emi o ha se si Jesu eniti a n pe ni Kristi” (Matteu 27 :22). Eleyi naa si ni ibeere ti Olorun yio beere lowo gbogbo wa ni igba ti a ba pa ipo da wipe ” Ki ni iwo se si ORUKO NAA, ani Oruko Jesu ?” Ti o ba gba Jesu nisinyi, iwo naa yo pelu awon ti won yo lo ayeraye won ni orun rere ninu alafia, itunu, ayo eyi ti ko se fi enu so. Ti o ba si ko, o lo ayeraye re ninu ibanuje, irora, ekun, ipayinkeke to ga lopolopo.
Ti o ba fe pe Jesu sinu aye re, gba adura yi pelu gbogbo okan re ” Jesu Olufe, mo gba wipe iwo ni omo Olorun, ko si oruko miran nipase eyi ti a fi le gba eniyan la yato si oruko re. O ku fun ese mi, o si jinde lati gba mi la. Dari gbogbo ese mi ji mi wemimo pelu eje re iyebiye. Wa si inu aye mi ki o si je Oluwa mi tit laelae. O se Jesu nitori o ti gba mi la.
Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi
Produced and Distributed by
GOSET MEDIA MINISTRIES
]]>Je ki n fi ye o dajudaju wipe otito ni ise ti mo fe je fun o yi nitoripe Oluwa lo so be. Nigba ti Olorun ba se ileri, o le gbokan le nitori pe awon ileri re ko le kunna lai lai. Olorun ko ni mu o gba oro yi gbo, ipinnu ati gba oro yi wa ni owo iwo gangan, sugbon a o ka si o lorun nitoripe o ti gbo.
Ipinnu ti o gbodo se funra re ni ipinnu yi nitoripe ise ti a ran mi si o yi ise ti o gbodo je funra re ni. O ni lati so wipe ”Mo gba” tabi ”Mio gba”.
” Nitori Olorun fe araye to bee ge, ti o fi omo bibire kan soso funni, ki enikeni ti o be gba a gbo ma ba segbe, sugbon ki o le ni iye ainpekun” Johannu 3 :16.
Nje o ti gbo oro iyanu yi ri rara ?
Duro jee ki o ronu si awon oro ese Bibeli yi. Won se afihan awon otito meta.
Akoko, ”Olorun fe araye to bee ge”! Niwon igba ti o wa ni aye, Olorun feran re. Ti eleyi ko ba jo e loju, ranti wipe nigba ti Olorun feran re,O feran elese ni yen! Bibeli so wipe gbogbo wa ni a ti se (Romu 3:23). Ti o ba je olooto iwo naa yio gba eyi pelu mi.
Bi o tile je pe Olorun feran re, o korira ese ti o nda. Nitori wipe Olorun je mino, o gbodo fi ijiya fun ese. O gbodo la ona mimo fun abayo ati lati gba awon elese la.
Bi ko ba si eleyi, elese yi o san idiyele tabi iya fun ese re ni eyi ti o tumo si wipe yio lo ayeraye re ninu ina orun apaadi. (ifihan 20 :15).
Otito keji ni eyi ” O fi omo bibi re kan soso funni”! Olorun feran re to bee ge ti o fi ran omo re wa si aye lati ku lori igi agbelebu ki iwo le ba ni iye.
Se o mo pe enikan gbodo san ijiya ese, o le je iwo tabi enikan ti ko ni ese lorun rara ti a o fi paro fun o. Olorun fi omo re kan soso Jesu Kristi gege bi ipaaro ti ko ni ese. O ta eje re sile ki a le mu ese tire kuro, ki o si le ni iye ainipekun.
Otito keta si ni eyi, ”Enikeni ti o ba gbagbo ma baa segbe, sugbon ko le ni iye ainipekun” Ronu sii, Olorun maa fi iye ainipekun fun gbogbo eni ti o ba gba Jesu Kristi gbo. Olugbala ti ” pari” ise naa. O ti ku. O ti jinde kuro ni isa oku, o si ti pada lo si oke orun. Ipa tire lo ku wipe ki o gbagbo ninu re.
Eyi tumo si wipe ki o gba wipe elese ni o,si ri mo daju wipe Jesu ti san gbogbo ijiya fun ese re, ki o si gba gege bi Oluwa ati Olugbala re. Ise naa ti mo wa je fun o ni eleyi.
Nisinyi, o gbodo se ipinnu. Se o gba tabi o o ko ni gba? Se o gbagbo ninu re tabi o o ko?
Ronu nipa re ni eekan si :
Nitori Olorun fe araye tobee ge, ti o fi omo bibi re kan soso funni, ki enikeni ti o gba a gbo ma ba segbe, sugbon ko le ni iye ainipekun.” Johannu 3 :16
Akoko re ni ile aye yi kuru sugbon ipinnu ti o ba se fun Kristi yio wa titi lailai. Se o gba Jesu Kristi gege bi Olugbala ki o si ni idaniloju iye ainipekun ?.
Ti o ba fe gba Jesu bi Oluwa ati Olugbala, jowo gba adura yi nitooto lati inu okan re wa ”Jesu Oluwa, mo gbagbo wipe o ku fun ese mi, a si ji o dide fun idalare mi. Dari ese mi ji mi ki o si we mi nu mo pelu eje re iyebiye wa si inu aye mi ki o si je Oluwa lati oni lo.
E seun Jesu nitoripe e ti gba mi la. Amin.”
Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi
Produced and Distributed by
GOSET MEDIA MINISTRIES
]]>Ni ojo kan iwo yio fi aye yi sile. Iwo yio si duro ni iwaju Olorun “Niwon bi a si ti fi lele fun gbogbo eniyan lati ku lekan soso, sugbon leyin eleyi idajo” (Heberu 9:27). Ti o ba ku ti o si ba ara re ninu irora orun apadi, TANI IWO YIO DA LEBI?
O ko le da Olorun lebi, nitori ki i se ife Olorun ni ki enikeni ki o segbe; sugbon ki a ni iye ainipekun (Johannu 3:16).
O ko le da Kristi lebi, nitori Jesu Kristi wa si inu aye yi lati gba elese la (1Tim. 1:15) “Otito ni oro naa, o si ye fun itewogba, pe Kristi Jesu wa si aye lati gba elese la”.
“Nitori ti Kristi pelu jiya leekan nitori ese wa. Olooto fun awon alaisooto, ki o le mu wa wa si odo Olorun” (1Peteru 3:18).
O ko le so wipe o ti pa ofin re mo nitori Olorun so wipe “Nitori enikeni ti o ba pa gbogbo ofin mo , ti o si ru okan , o jebi gbogbo re” (Jakobu 2:10). A fi ofin kale ki a le mo wipe a nilo Olugbala. O wa tumo si wipe nipa ise ofin , ko si eni ti a o da lare ni iwaju re nitori pe nipa ofin ni a mo ese. (Romu 3 : 20).
O ko ni awawi Kankan nipa siso wipe “o se iwon ti o le se”, “mo ma n lo si ile ijosin” “mo ma n san awon owo to to si mi” “mo ma n gbadura” “n ko tile buru pupo naa”. O tile tun le so wipe “Olorun dara ju ki o fi eniyan si inu ina orun apaadi lo, kin ni mo se to to eleyi” Rara o, ore mi , bi o se wu ki didara re dara to, ko i ti dara to fun Olorun. Bibeli so wipe “gbogbo akisa wa si da bi aso elegbin” (Isaya 64:6). Ko si eni ti o n se rere, ko tile si enikan”. (Romu 3:12). Ki ise nipa ise ti awa se ninu ododo, sugbon gege bi aanu ni o gba wa la (Titu 3:5)
O ko le so wipe a ko ti kilo fun o. Oro Olorun ni ikilo fun o. o si n gbo lowo lowo bayi “Enikeni ti ko ba gbagbo ninu oruko omo bibi kan soso ti Olorun ni a ti da lejo” (Johanu 3:18).
O ko ni awawi Kankan. Ti o ba di ojo idajo, se Kristi yo gba o gege bi okan ninu awon omo re? tabi o gba idajo ti o wi pe “lo kuro lodo mi, iwo onise ese, emi ko mo o ri”.
O tun le so wipe opolopo akoko wa lati yanju oro yi nitori Olorun so wipe “Mase leri ara re niti ojo ola, nitori iwo ko mo oun ti ojo kan yio hu jade” (Owe 27:1) “Kiyesi i, nisinsinyi ni ojo igbala. (2 Korinti 6:20)
Jewo ese re fun Olorun, ki o si gba Jesu Kristi Oluwa gbo, a o si gba o la.
O le so wipe o ko gbagbo ninu gbogbo eyi, sugbon eleyi ko din nkankan ku ninu awon otito ti mo ti fi ye o yi. Ojuse ati se ipinnu lati lo ayeraye re ni orun apadi je ti re nikan. Ipinnu yato si ise, isesi re ni yo so ibi ti o ti lo ayeraye re.
ARA RE NIKAN NAA NI WA DA LEBI ti o ba ko lati to Jesu Kristi wa fun idariji ati igbala kuro ni owo ese. O ti so wipe “eni ti o ba si to mi wa emi ki yio taa nu, bi o ti wu ki o ri”. (Johannu 6:37). Wa si odo re loni ki o si gbekele lati gba o kuro lowo ese ati gbogbo ijiya re.
Ti o ba fe gba Jesu ni Oluwa ati Olugbala, jowo gba adura yi nitooto lati inu okan re wa “Jesu Oluwa, mo gbagbo wipe O ku fun ese mi, a si ji O dide fun idalare mi. Dari ese mi ji mi ki O si we mi mo pelu eje re iyebiye. Wa si inu aye mi ki O si je Oluwa mi lati oni lo. E seun Jesu, nitori pe, E ti gba mi la.
Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi
Produced and Distributed by
GOSET MEDIA MINISTRIES
]]>
Bawo ni mo se mo ?. Mo mo nitoripe Jesu Kristi, eni ti o wa lati orun ri gbogbo re patapata, o so ni opolopo igba ninu Bibeli ti ko si le paro rararara. O so itan awon okunrin meji kan fun wa, Lasaru ati oloro, won gbe ni aye yi. Sugbon nigba ti o ya won ku (Luku 16 :19-31). Lasaru lo si orun rere nigbati oloro lo si orun apaadi. Oloro yi kigbe ni orun apaadi ” Baba Abrahamu saanu fun mi, ki o si ran Lasaru, ki o te orika re bomi, ki o si fi tu mi li ahon, nitori emi njoro ninu owo ina yi” (vs 24) Abrahamu si da lohun wipe ” Omo ranti pe nigba aye re, iwo ti gba rere tire, sugbon nisinsiyi ara ro Lasaru iwo si njoro” (vs 25)
Lati inu ibi kika yi, a ri ohun meji, pataki nipa orun rere ati orun apaadi. Akoko orun je ibi itura ati ayo ti ko lopin fun awon OLODODO nikan. Orun ni ibugbe Olorun. O je ibi ailafiwe nibi ti awon olodoodo yio ti bo lowo gbogbo idaamu, wahala, ajalu ati beebelo ni be, ”Olorun yio si nu omije gbogbo nu kuro li oju won, ki yio si si iku mo, tabi ofo, tabi ekun, beeni ki yio si irora mo, nitoripe oun atijo ti koja lo ”(Ifihan 21 :4)”. Ona igboro ilu naa si je kiki wura” (Ifihan 21 :21). Ile itura ti o dara ju ni agbaye ko se se akawe awon ile didara ti o wa ni orun (Johanu 14 :2) ”. Oru ki yio si mo, won ko si ni wa imole fitila tabi oorun, Oluwa Olorun ni yio tan imole fun won” (Ifihan 22 :5) ko si oro naa ti a le fi se apejuwe ni kikun nipa ogo ati itura orun rere.
Ekeji, orun apaadi naa je ibi ti o wa dajudaju fun ijiya awon ALAISODODO ”nibiti kokoro won ki ku, ti ina naa ki si ku” (Marku 9 :46-47). Olorun ko da orun apadi fun eniyan, a da fun esu ati awon angeli re. (Matteu 25:41) sugbon opolopo eniyan ni won o lo si ibe nitori ainigbagbo ati aimokan. A gbodo je ki o mo wipe ko si agbedemeji, laarin orun rere ati orun apaadi. Ko si ibi iwenumo Kankan ti a ti ma n we ese eniyan nu “ niwon bi a si ti fi lele fun gbogbo eniyan lati ku leekan soso, sugbon leyin eyi idajo” (Heberu 9:27).
Ninu aanu re nla, Olorun ti fi aye gba ogoro eniyan kaakiri agbaye lati ni iriri orun rere ati orun apaadi ki won si pada wa si aye lati kilo fun wa. Lara won ni Robert Liardon, ninu akosile re to pe ni “mo ri Orun (www.robberliardon.org) Mary Baxter ”Ifihan orun lati orun wa” (www.mbaxterdivinerevelation.org) (Choo Thomas “Orun ma daju gan ni” choothomas.org) pelu Augustus Chidozie ti o je omo orile ede Najiria ti o ku fun ojo merin ti o si ti wa si aye pada. Ju gbogbo awon iriri yi lo, ohun agba iyanu kan sele ni bi odun 1989 ni ile Russia, nibi ti gbogbo eniyan mo wipe awon ara ibe ko gba Olorun gbo. Awon onimo sayensi kan ti won je omo ile Russia ni won gbe ile ni Siberia to maili mesan tabi ibuso kilomita merinla. Gbigbona inu iho yi to 2000^F (1,090^c) Ero gbohun gbohun won si gbe ohun ariwo awon eniyan ti won wa ninu iroira ati iya nla ninu iho ile naa, eleyi fi idi akosile ninu Bibeli wipe isale aye yi ni orun apaadi wa (Efesu 4:9-10).
Ibeere pataki ti ologbon eniyan yo wa fi iye si ni wipe “Bawo ni mo se le de orun rere? Jesu nikan ni ona si orun rere. O so wipe ” Emi li ona ati otito ati iye, ko si enikeni ti o le wa sodo Baba bikose nipase mi” (Johannu 14 :6). Oun nikan ni ona si orun rere nitori iku re lori agbelebu lo se ilaja laarin awa ati Olorun (2 Korinti 5 :19). Gbogbo eniyan patapata ni elese nitori ese Adamu, baba nla gbogbo eniyan (Romu 3 :23). Iku si ni ijiya fun ese (Romu 6 :23). Sugbon Olorun ko ni idunnu si iku elese (Esekiel 33 :11). Nitori naa ni o se ran omo re nikan soso Jesu Kristi lati ku dipo wa (1 Peteru 3 :18) nitori wipe lai si itajesile ko le si idariji ese (Heberu 9 :22). Eje Jesu ti o se iyebiye nikan ni o le so eniyan di OLODODO niwaju Olorun, ki i se ise owo wa ti o dabi akisa elegbin niwaju Olorun (Aisaya 64 :6).
Ara mi, mo pe o loni lati jowo aye re fun Jesu ki o le ba lo ayeraye ni orun rere pelu re. Ti o ba ko ipe yi, o o lo ayeraye re ni inu ina apaadi. Ipinu yi je eyi ti iwo nikan le se fun ara re ; Ti o ba fe fi aye re fun Jesu, jowo gba adura yi tokan tokan ” Jesu Oluwa mo gbagbo wipe iwo nikan ni ona si orun. O ku o si tun jinde lati gba mi la. Dari gbogbo ese mi ji ki o si fi eje re iyebiye we mi nu mo. Wa si inu aye mi ki o si joba nibe lailai. O se ti o gba okan mi la. Amin.
Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi
Produced and Distributed by
GOSET MEDIA MINISTRIES
]]>Jowo duro je e na fun iseju kan ki o si ronu nipa irin ajo pataki kan ti o ti lo ri tabi igba ti o se se ki o de ilu tuntun tabi orile ede ti o yato si orile ede re. Nigba ti o bere irin ajo yi, se o kan bo si inu oko ofurufu tabi oko ti yio gbe o lo lo ba gbera fun irin ajo naa ?
O daju pe bee ko lo se se. Ki o to bere irin ajo na, o ti fi owo pamo ki o to lati lo fun irin ajo naa, o o di eru ti o to fun o lati lo ni irin ajo, o o se eto ti o to fun ibi ti o wo si lati sun ati de si pelu gbogbo orisirisi ipalemo ti o ye lati mu ki irin ajo naa ko yori si rere.
Oun ti o ya eniyan lenu ti o si se ni laanu nipe opolopo eniyan ma nse ipalemo fun irin ajo inu aye ti o je aremabo ti enikeni ko si le se alaimalo. Opolopo wa la dabi oba kan ninu itan kan eni to fun akinyeye/omugo ti o wa ni afin re ni opa ase re. Kabiyesi so fun omugo yi pe ki o fi opa ase re yi fun enikeni ti o ba ri ti o ya omugo ju u lo. Arakunrin omugo yi gbiyanju titi lati se awari eni ti o go ju ara re lo sugbon gbogbo igbiyanju re ja si pabo nitori ko ri eni ti o go ju oun lo. Laipe leyin akoko yi ni oba ilu yi se aisan to po gidigidi de oju iku. Okunrin omugo yi bere lowo oba iru ipalemo ti o ti se fun irin ajo aremabo eyi ti o fe lo sugbon oba so fun wipe oun ko se ipalemo kankan. Eleyi lo si mu ki okunrin omugo yi fun oba ni opa ti oba f un tele wipe nitooto oba yi go gidigidi ju oun lo. Abi e ko ri eko nla itan yi.
Ile aye ti a wa yi je ipalemo fun eyi ti o nbo. Iku re ko ni opin aiye re, irim ajo re yo tun te siwaju ni ayeraye ti ko ni opin. Bi o tile pe laye ti o lo opolopo odun, o lo ju be lo ni ayeraye. Bi aye eyi ti a wa yi fun wa ni anfani lati yan nkan to wu wa ninu opolopo nkan towa nibe, ayeraye ko ni ju nkan meji lati yan okan ninu re lo eyi si ni orun rere tabi orun apadi. ” Ati opolopo ninu awon ti o sun ninu erupe ile ni yio ji, awon miran si iye ainipekun ati awon miran si itiju ati egan ainipekun” (Daniel 12 :2). Ibasepo ti o wa larin iwo ati Olorun nigba ti o wa laye ni yio so ibi ti wa ti lo ayeraye re. Ti o ba ni ibasepo pelu Olorun ni aye yi nipase omo re Jesu Kristi, o lo ayeraye re pelu Olorun ninu ayo nla ati idunnu ti ko se fi enu so. Ti ko ba si ribe, orun apadi nibi ti iya ati idaamu po ju si ni yio je ipin re.
Ki ni idi ti o fi gbodo ni ibasepo pelu Olorun nipase Jesu Kristi ki oba le da orun ? idi re ni wipe gbogbo eda eniyan patapata lo ti wo inu wahala pelu Olorun nitori ese baba nla wa Adamu, Gbogbo eniyan li o sa ti se, ti won si kuna ogo Olorun” (Romu 3 :23). Ijiya fun ese si ni iku (Romu 6 :23). Sugbon Olorun ko ni inu didun si iku elese (Esekieli 33 :11) Nitorina Olorun ran omo re Jesu Kristi lati wa ku ni ipo wa ” Nitori ti Kristi pelu ijiya leekan nitori ese wa, olooto fun awon alaisooto, ki o le mu wa de odo Olorun, eniti a pa ninu ara, sugbon ti a so di aaye ninu Emi” (1 Peteru 3 :18). Iku Jesu Kristi ni o se ilaja laarin awa ati Olorun (2 Korinti 5 :19). Nipase iku Jesu Kristi lori igi agbelebu a pa gbogbo ese wa re patapata nitori wipe laisi itajesile ko si idariji ese (Heberu 9 :22).
Orun je ibi ti a ti pese sile fun awon ti won ti palemo fun. Yato si awon irin ajo ile aye yi, o ko nilo lati mu ounkoun dani lo si irinajo aremabo yi ” Nitori a ko mu ohun kan wa si aye, beeni a ko si le mu ohunkohun jade lo” (1 Timoteu 6 :7) Gbogbo oun ti o nilo ni Jesu Kristi ti se ipalemo re fun o ”Ninu ile Baba mi, Opolopo ibugbe li o wa, iba ma se bee, emi iba ti so fun yin. Nitori emi nlo ipese aye sile fun yin (Johannu 14 :2).
IPALEMO ti o nilo lati se ni lati jowo aye re fun Jesu Kristi. Ibeere kan ti yo ko gbogbo wa loju lati odo Olorunn leyin aye yi ni wipe “Ki ni o se nipa ebun omo mi ti mo fi fun o nigba ti o wa ni aye?”
Ara Oluka oro yi, o ni lati wa ojutu si ibeere yi ni isinsiyi. Se o fe gba Jesu ni tabi o fe koo ? ipinnu yi wa ni owo re. Ipinnu ti o ba si se ni yio so ibi ti wa ti lo ayeraye re boya ni orun rere ni tabi orun apaadi. Ti o ba fe jowo aye re fun Kristi, dakun fi tokatokan gba adura bayi ” Jesu Oluwa , mo gbagbo wipe iwo ni omo Olorun. O ku o si tun jinde lati gba mi la. Dari gbogbo ese mi ji mi ki o si fi eje re iyebiye ni we mi mo. Wo inu aye mi wa ki o si ma je Oluwa mi lati oni lo. O se ti o gba mi la. Amin’’
Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi
Produced and Distributed by
GOSET MEDIA MINISTRIES
]]>Ni bi ogorun odun seyin (15th April, 1912) isele imu iku ba ni loju omi to ga julo ni agbaye sele. Oko oju omi to tobi kan ti won n pe ni “Titanic” ti o si ni ero to le ni egberun meji (2,224) ninu re ni o ri sinu agbami okun ninu irin ajo re akoko lati Southampton, England lo si New York ni orile ede Amerika ti o si je wipe eniyan egberun kan aabo (1,500) ninu awon to wa ninu oko oju omi naa ni o ku ninu isele naa.
“Titanic” tumo si oun ti o tobi ti o si gborin gan. Nitooto, oko oju omi yi tobi pupopupo gan ni. Oko oju omi yi ni aja mewa ti o si ni gbogbo nkan amayederun ti a le ri ni ile igbafe ti o dara ni agbaye. Won tile ri oko oju omi yi gege bi eyi ti o tobi ju, ti o lagbara ju , ti o si tun wa ni ailewu julo ni gbogbo agbaye. Nitori gbogbo awon nkan arimuye yi lo je ki eni ti o ni oko oju omi naa pe ni oko oju omi ti Olorun paapa ko le je ki o ri. Sugbon Olorun alagbara, eni ti o ti “yan awon oun ailera aye yi lati fi daamu awon ohun ti o lagbara”(1 Korinti 1:27)gba omi didi tabi yinyin laaye lati mu oko oju omi nla naa ri sinu omi. Eko nla ti a koko ko nipa bi oko oju omi nla yi se ri ni wipe oruko Olorun ni owo ju oun ti enikani le ma fi tayin tabi fi se esin. Dipo re, a gbodo ma fi owo ati ola fun(Aisaya 8:13). Orisirisi eniyan lo wa ninu oko oju omi naa, awon olowo, gbajumo, otokun ilu, okunrin, obinrin, omode, ebi ati awon osise inu oko naa. Ki o to di wipe oko oju omi yi bere irin ajo yi, orisirisi nka lo se pataki bi se olowo ni won tabi talaka, se awon osise wa ni enu ise ni tabi won wa ni isinmi, obirin ni won ni tabi okunrin, won ni eru pupo ni tabi eru won mo ni iwonba. Nigba ti oko oju omi yi ri tan, ko si ikankan ninu awon nkan wonji to se pataki mo. Oun meji pere lo wa se pataki se won ye ni tabi won ti sonu patapata. Ile ise ti o se oko oju omi yi “White Star Company” gbe atejade oruko jade, ona meji pere ni won pin oruko gbogbo awon ti won wa ninu oko naa si “Awon ti o sonu” tabi “Awon ti o ye”. Eko nla tun ni eyi lati ara isele yi.
Ara mi, bi Olorun naa se nwo gbogbo eniyan ni agbaye naa loni niyi, bakanna ni yo se ri won ni aye ti o nbo wa -“O sonu ni tabi o ye”. Ni oju iku, ko si oun kankan ti a ni laye yi ti yo se pataki mo. Wipe o je okunrin, olowo, eniyan dudu tabi funfun, talaka, omowe tabi ope. Oun ti yo se pataki nigba ti o ba pade eleda re ni pe se “O sonu ni tabi o ye”. Gbogbo eniyan lo ti sonu sinu ese “Gbogbo wa ti sina kirikiri bi aguntan, olukuluku wa tele ona ara re”(Aisaya 53:6). Sugbon iroyin ayo kan wa fun o “Nitori omo eniyan de lati wa awon ti o nu kiri “ (Luku 19:10). Bibeli tun so wipe “Yio si bi omokunrin kan, JESU ni iwo o pe oruko re, nitori yio gba awon eniyan re la kuro ninu ese won”(Matiu 1:21).
Ti o ba fi aye re fun Jesu, a o gba o la kuro lowo ibinu ti o nbo wa, gege bi awon ti o ye ninu oko oju omi TITANIC. A o ko oruko re sinu iwe iye (Ifihan 20:15) o si wa lo wa pelu re ni orun ni ibi ti ayo ailefenuso wa pelu ogo nla. Fun awon elese ti o ti sonu ti won si ko lati fi aye won fun Jesu ni won o ri titi laelae gege bi awon ti won fi aragba ninu iparun TITANIC. Inu adagun ina ti o njo pelu sulfuri ni ipin awon wonyi titi ayeraye.(Ifihan 20:10-15). Iwo funra re ni o le yan eyi ti o ba wu o. Ti o ba fe fi aye re fun Jesu, gba adura yi pelu gbogbo okan re “Jesu Oluwa, mo gbagbo wipe iwo ni omo Olorun. O ku fun ese mi, o si jinde fun idalare mi. Dari ese mi ji mi ki o si fi eje re iyebiye ni we mi nu mo. Wa si inu aye mi ki o si je Olorun mi lati oni lo. O se Jesu nitori o ti gba mi la. Amin”.
Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi
Produced and Distributed by
GOSET MEDIA MINISTRIES
]]>Ni ilu kan, awon jagun-jagun fe pa awon eya kan run. Lati se ise ibi yii, olori ogun ilu na pase wipe gbogbo awon eniyan ti o wa ninu ilu naa ni ki a ta eje re sile.
Lati ri wipe ko si ile kan ti a ko fi owo kan, awon olote jagunjagun yi bere lati ma fi eje awon ti won ba ti pa si enu opo enu ilekun ile won. Okunrin kan laarin ilu naa gbo nipa eyi. O yara pa ewure kan o si fi eje re si ara opo enu ona ile re. Nigbati awon jagunjagun si ri eje ni enu opo enu ona ile re, won re ile naa koja ni ero wipe awon ti se ise ibi won ninu ile naa. Bi iku se fo awon olugbe ile naa koja niyi.
Iru itan yi ni ohun ti osele ninu Bibeli ni egberun meji odun o le die sehin. Iwo gan le ni imo nipa itan yii, Olorun so fun Farao oba Egipti wipe ki o jowo awon omo Israeli lati jade lo lehin ti won se atipo ni ile re fun bi ogbon o le ni irinwo odun. Sugbon o ko jale. Ni asale ojo ti Olorun fe fi owo agbara nla gba won, O pase fun awon omo Israeli ki won ki o pa odo agutan ti ko ni abawon ki won ki o si fi eje re si ara opo enu ona ati aterigba ile won (Eksodu 12:7). Olorun se ileri wipe “Eje yi ni yoo je ami fun yin ninu ile ti e ngbe. Nigbati mo ba si ri ami eje naa, emi yoo re yin koja; ibi naa ki yoo si wa si ori yin lati run yin nigbati mo ba la ile Egipti koja” Eksodu 12:13,23). Ni oru ojo naa, akobi eniyan ati ti eranko ni a pa run (Ekso. 12:29). Ko si okankan ninu omo Israeli ti a fi owo kan nitori ami eje naa.
Ohun ti o sele ninu iwe Eksodu je awojiji tabi itokasi ohun ti Olorun yoo se nipase Jesu Kristi ninu majemu titun (Heberu 10:1). Jesu ni odoaguntan alailabawon naa (Eksodu 12:5). Johannu nigbati o nso nipa Jesu so wipe “Woo Odoaguntan Olorun, eni ti o ko ese araiye lo (Johannu 1:29). Jesu ni odoaguntan fun irekoja wa. (1Korinti 5:7)
Ese ti Bibeli nso nipa re ni eyi ti a jogun lati odo Adamu. Nipase Adamu ni gbogbo eniyan fi di elese (Rom 3:23) bee si ni iku ni ere se (Romu 6:23). Nitori idi eyi, gbogbo wa ni o ye lati ku; ti o tumo si lilo ayeraye ninu ina orun apadi. Sugbon ife ni Olorun. Ko ni inu didun si iku elese. (Ezekieli 33:11) Nitori naa ni o se ran ayanfe omo re Jesu Kristi lati ku fun ese wa. O ta eje re iyebiye sile fun wa nitoripe laisi itajesile, imukuro ese ko si(Hebrew 9:22). Bi o ba gbagbo ninu Jesu Kristi, bi o ti wu ki ese re po to. Eje Jesu Kristi n we ese nu (1John 1:7).
Eje Jesu nsise takuntakun ninu, lode ati titi ayeraye fun awon ti o ba gbaa gbo. O nse iwenumo to daju kuro ninu idalebi ati ero buburu okan.
Ni ita awon onigbagbo ni ami eje Jesu ti orun ati orun apadi da mo. Gege bi eje lara opo enu , o ndabobo kuro ewu ati ohun buburu ti o wa ni aye yi. Ju gbogbo re lo, eje yi ni iwe irina si ayeraye (orun) nitori ti Jesu ti ra irapada fun awon onigbagbo nipa eje Re (Hebrew 9:12). Awon ti o ba ko irapada yi yoo lo ayeraye won ni orun apaadi.
Ore mi oluka iwe yii, akoko niyi fun o lati se ipinu lati gba Jesu ki o si wa si abe eje naa fun igbala ati abo tabi ki o ko o. Bi o ba fe gba Jesu sinu aye re, jowo gba adura yi “Jesu Oluwa, mo gbagbo pe o ta eje re iyebiye sile fun mi, O ku, o si tun jinde lati gba mi la. Dari ese mi ji mi, ki O si we mi mo pelu eje Re. wa si inu aye mi ki o si maa joba nibe lati isisiyi lo. O seun Jesu fun igbala mi” Amin.
Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi
Produced and Distributed by
GOSET MEDIA MINISTRIES
]]>
Sugbon, ohun meji ni o nilati wa ni imuse ki idariji naa to le fi ese mule. Aare gbodo na owo idariji si awon ojiya naa ki awom ojiya naa si setan lati gba idariji yi.
Ni ibamu pelu ero ti eniyan, awon yoku fi ayo gba idariji yi, a tu won sile, won si fi ayo darapo mo awon ebi won. Si iyalenu awon eniyan, odomokunrin yi ko lati gba idariji Aare. Niwon igbati ohun meji ti o ni lati sele ki idariji to fi ese mule ko si ni imuse, a pa okunrin odaran yii. Okunrin yi ku, ki ise pe a ko dariji sugbon nitori ti o ko lati gba idariji.
Itan yi so fun wa ibasepo ti o wa laarin eniyan ati Olorun. Gbogbo eniyan gege bi awon odaran merin yii lo ti se ti o si ti kuna ogo Olorun (Rom. 3:23). Ese ti a n so nipa re yi, a jogun re lati odo Adamu eniti se orisun gbogbo eda alaaye. Ese Adamu li o fa ese gbogbo eniyan. Bibeli, oro Olorun so wipe “Nitori naa nipase ese enikan, idajo wa si ori gbogbo eniyan eyiti o mu idalebi wa” (Rom. 5:18). Eyi tumo si pe Adamu se, a si jogun ese naa nipase oruko ati eje ti o n lo lati iran kan si omiran. Iwa mimo Olorun nbere wipe elese gbodo jiya nitoripe “iku ni ere ese” (Rom. 6:23). Nitori naa, gbogbo eniyan gege bi awon odaran inu itan yi ni a ti dajo iku fun.
Sugbon, Olorun je olufe, oloore ofe ati alaanu ti ko ni inu didun ni iku elese (Eze. 33:11). Gbo bi Olorun se fi eyi han, oro re so wipe “Nitori ti Olorun fe araye to bee ge to fi omo bibi re kan soso fun w a pe enikeni ti o ba gbagbo, ki o ma ba segbe, sugbon ki o le ni iye ainipekun (Johannu 3:16). Niwon igbati o wa ninu aye, Olorun feran re. Ko fe ki o ku. Nitori bee ni o se ran omo re Jesu Kristi lati ku ni ipo re, “Nitori ti Kristi pelu jiya leekan nitori ese wa, olooto fun awon alaisooto ki o le mu wa de odo Olorun” (1Pet. 3:18). Nitori Jesu Kristi san idiyele fun ese wa, nipase eje Re owon, a ti dariji iwo oluka iwe yi, gege bi Aare ile Amerika ni, Olorun ni abe oore ofe n fun o ni idariji fun ese re nipase Jesu Kristi. Sugbon o ni lati gba nipa yiyan ki o to le wa si imuse. Gege bi awon odaran ni, ogunlogo eniyan ni o ti gba ebun yi nipa igbagbo ninu Jesu Kristi, won n yo nisisinyi, won si ti di ominira. Mase ko ebun oore ofe yi bi odomokunrin yi” nitori bawo ni a se le bo bi a ba ko igbala nla (Heb. 2:3). Ijiya fun kiko ebun ofe yi bi oodomokunrin yi ni iku, eyi jasi lilo ayeraye ni ina orun apadi.
Tire ni lati yan. N je o fe ko tabi gba ebun naa? Bi o ba fe gba ebun oore ofe idariji yi, jowo fi tokantokan gba adura yi. Jesu Oluwa, mo gbagbo pe O ku fun ese mi, a si ji O dide fun idalare mi. Dari ese mi ji mi ki O si we mi pelu eje iyebiye Re wa sinu aye mi ki O si maa joba lati isisinyi lo. O seun Jesu ti o gba mi la.
Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi
Produced and Distributed by
GOSET MEDIA MINISTRIES
]]>