TANI IWO YIO DA LEBI?

 

Ni ojo kan iwo yio fi aye yi sile. Iwo yio si duro ni iwaju Olorun “Niwon bi a si ti fi lele fun gbogbo eniyan lati ku lekan soso, sugbon leyin eleyi idajo” (Heberu 9:27). Ti o ba ku ti o si ba ara re ninu irora orun apadi, TANI IWO YIO DA  LEBI?

 

O ko le da Olorun lebi, nitori ki i se ife Olorun ni ki enikeni ki o segbe; sugbon ki a ni iye ainipekun (Johannu 3:16).

 

O ko le da Kristi lebi, nitori Jesu Kristi wa si inu aye yi lati gba elese la (1Tim. 1:15) “Otito ni oro naa, o si ye fun itewogba, pe Kristi Jesu wa si aye lati gba elese la”.

 

“Nitori ti Kristi pelu jiya leekan nitori ese wa. Olooto fun awon alaisooto, ki o le mu wa wa si odo Olorun” (1Peteru 3:18).

 

O ko le so wipe o ti pa ofin re mo nitori Olorun so wipe “Nitori enikeni ti o ba pa gbogbo ofin mo , ti o si ru okan , o jebi gbogbo re” (Jakobu 2:10). A fi ofin kale ki a le mo wipe a nilo Olugbala. O wa tumo si wipe nipa ise ofin , ko si eni ti a o da lare ni iwaju re nitori pe nipa ofin ni a mo ese. (Romu 3 : 20).

 

O ko ni awawi Kankan nipa siso wipe “o se iwon ti o le se”, “mo ma n lo si ile ijosin” “mo ma n san awon owo to to si mi” “mo ma n gbadura” “n ko tile buru pupo naa”.  O tile tun le so wipe “Olorun dara ju ki o fi eniyan si inu ina orun apaadi lo, kin ni mo se to to eleyi” Rara o, ore mi , bi o se wu ki didara re dara to, ko i ti dara to fun Olorun. Bibeli so wipe “gbogbo akisa wa si da bi aso elegbin” (Isaya 64:6). Ko si eni ti o n se rere, ko tile si enikan”. (Romu 3:12). Ki ise nipa ise ti awa se ninu ododo, sugbon gege bi aanu ni o gba wa la (Titu 3:5)

 

O ko le so wipe a ko ti kilo fun o. Oro Olorun ni ikilo fun o. o si n gbo lowo lowo bayi “Enikeni ti ko ba gbagbo ninu oruko omo bibi kan soso ti Olorun ni a ti da lejo” (Johanu 3:18).

 

O ko ni awawi Kankan. Ti o ba di ojo idajo, se Kristi yo gba o gege bi okan ninu awon omo re? tabi o gba idajo ti o wi pe “lo kuro lodo mi, iwo onise ese, emi ko mo o ri”.

 

O  tun le so wipe opolopo akoko wa lati yanju oro yi nitori Olorun so wipe “Mase leri ara re niti ojo ola, nitori iwo ko mo oun ti ojo kan yio hu jade” (Owe 27:1) “Kiyesi i, nisinsinyi ni ojo igbala. (2 Korinti 6:20)

 

Jewo ese re fun Olorun, ki o si gba Jesu Kristi Oluwa gbo, a o si gba o la.

 

O le so wipe o ko gbagbo ninu gbogbo eyi, sugbon eleyi ko din nkankan ku ninu awon otito ti mo ti fi ye o yi. Ojuse ati se ipinnu lati lo ayeraye re ni orun apadi je ti re nikan. Ipinnu yato si ise, isesi re ni yo so ibi ti o ti lo ayeraye re.

ARA RE NIKAN NAA NI WA DA LEBI ti o ba ko lati to Jesu Kristi wa fun idariji ati igbala kuro ni owo ese. O ti so wipe “eni ti o ba si to mi wa emi ki yio taa nu, bi o ti wu ki o ri”. (Johannu 6:37). Wa si odo re loni ki o si gbekele lati gba o kuro lowo ese ati gbogbo ijiya re.

 

Ti o ba fe gba Jesu ni Oluwa ati Olugbala, jowo gba adura yi nitooto lati inu okan re wa “Jesu Oluwa, mo gbagbo wipe O ku fun ese mi, a si ji O dide fun idalare mi. Dari ese mi ji mi ki O si we mi mo pelu eje re iyebiye. Wa si inu aye mi ki O si je Oluwa mi lati oni lo. E seun Jesu, nitori pe, E ti gba mi la.

 

 

 

Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi

Produced and Distributed  by

GOSET MEDIA MINISTRIES

Leave a Comment

Your email address will not be published.