MO GBODO SO EYI FUN O

Mo mo ohun iyanu kan ti mo gbodo so fun o! O se pataki ki o le ba yi ojo ola re pada gege bi o se yi temi pada. Koda, ipinnu ti o ba se nipa re yio ni ipa to ga lori aye re ati leyin iku re.

Je ki n fi ye o dajudaju wipe otito ni ise ti mo fe je fun o yi nitoripe Oluwa lo so be. Nigba ti Olorun ba se ileri, o le gbokan le nitori pe awon ileri re ko le kunna lai lai. Olorun ko ni mu o gba oro yi gbo, ipinnu ati gba oro yi wa ni owo iwo gangan, sugbon a o ka si o lorun nitoripe o ti gbo.

 

Ipinnu ti o gbodo se funra re ni ipinnu yi nitoripe ise ti a ran mi si o yi ise ti o gbodo je funra re ni. O ni lati so wipe ”Mo gba” tabi ”Mio gba”.

” Nitori Olorun fe araye to bee ge, ti o fi omo bibire kan soso funni, ki enikeni ti o be gba a gbo ma ba segbe, sugbon ki o le ni iye ainpekun” Johannu 3 :16.

 

Nje o ti gbo oro iyanu yi ri rara ?

Duro jee ki o ronu si awon oro ese Bibeli yi. Won se afihan awon otito meta.

Akoko, ”Olorun fe araye to bee ge”! Niwon igba ti o wa ni aye, Olorun feran re. Ti eleyi ko  ba jo e loju,  ranti wipe nigba ti Olorun feran re,O feran elese ni yen! Bibeli so wipe gbogbo wa ni a ti se (Romu 3:23). Ti o ba je olooto iwo naa yio gba eyi pelu mi.

Bi o tile je pe Olorun feran re, o korira ese ti o nda. Nitori wipe Olorun je mino, o gbodo fi ijiya fun ese. O gbodo la ona mimo fun abayo ati lati gba awon elese la.

Bi ko ba si eleyi, elese yi o san idiyele tabi iya fun ese re ni eyi ti o tumo si wipe yio lo ayeraye re ninu ina orun apaadi. (ifihan 20 :15).

 

Otito keji ni eyi ” O fi omo bibi re kan soso funni”! Olorun feran re to bee ge ti o fi ran omo re wa si aye lati ku lori igi agbelebu ki iwo le ba ni iye.

Se o mo pe enikan gbodo san ijiya ese, o le je iwo tabi enikan ti ko ni ese lorun rara ti a o fi paro fun o. Olorun fi omo re kan soso Jesu Kristi gege bi ipaaro ti ko ni ese. O ta eje re sile ki a le mu ese tire kuro, ki o si le ni iye ainipekun.

Otito keta si ni eyi, ”Enikeni ti o ba gbagbo ma baa segbe, sugbon ko le ni iye ainipekun” Ronu sii, Olorun maa fi iye ainipekun fun gbogbo eni ti o ba gba Jesu Kristi gbo. Olugbala ti ” pari” ise naa. O ti ku. O ti jinde kuro ni isa oku, o si ti pada lo si oke orun. Ipa tire lo ku wipe ki o gbagbo ninu re.

Eyi tumo si wipe ki o gba wipe elese ni o,si ri mo daju wipe Jesu ti san gbogbo ijiya fun ese re, ki o si gba gege bi Oluwa ati Olugbala re. Ise naa ti mo wa je fun o ni eleyi.

Nisinyi, o gbodo se ipinnu. Se o gba tabi o o ko ni gba? Se o gbagbo ninu re tabi o o ko?

 

Ronu nipa re ni eekan si :

Nitori Olorun fe araye tobee ge, ti o fi omo bibi re kan soso funni, ki enikeni ti o gba a gbo ma ba segbe, sugbon ko le ni iye ainipekun.” Johannu 3 :16

Akoko re ni ile aye yi kuru sugbon ipinnu ti o ba se fun Kristi yio wa titi lailai. Se o gba Jesu Kristi gege bi Olugbala ki o si ni idaniloju iye ainipekun ?.

Ti o ba fe gba Jesu bi Oluwa ati Olugbala, jowo gba adura yi nitooto lati inu okan re wa ”Jesu Oluwa, mo gbagbo wipe o ku fun ese mi, a si ji o dide fun idalare mi. Dari ese mi ji mi ki o si  we mi nu mo pelu eje re iyebiye wa si inu aye mi ki o si je Oluwa lati oni lo.

E seun Jesu nitoripe e ti gba mi la. Amin.”

 

 

 

Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi

Produced and Distributed  by

GOSET MEDIA MINISTRIES

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *