KO SI ORUKO MIRAN

Owe awon adulawo/eniyan dudu kan so otito wipe ona pupo lo wo oja. Nipa bi a ti se nlo aye yi, owe yi je otito de ipele kan. Ti a ba  wa ni ki a wo ona ti o lo si orun, owe yi jinna si otito pupopupo. Eleyi je ogbon omo eniyan eyi ti Olorun ti kilo fun wa nipa re. “ki gbogbo yin ki o mase  duro ninu ogbon eniyan bikose ninu agbara Olorun” (1 Korinti 2:5). ONA KAN pere ni o de orun”.

 

Bawo ni mo se mo eyi? Oro Olorun to je otito ti ko si le puro so lati ye wa yekeyeke ni opolopo igba. Ni igba kan Peteru eniti o je ojo ati oniberu fi igboya so fun awon olori Ju wipe ” Ko si igbala lodo elomiran nitori ko si ORUKO MIRAN labe orun ti a fi fun ni ninu eniyan nipa eyiti a le fi gba wa la”(Ise awon Aposteli 4:12). Peteru n so nipa Oruko Jesu ni ibi ti a ka yi igbala tumo si itusile kuro lowo Satani, ese ati si iye ainipekun. Fun awon eniyan kan ti won si gbagbo ninu eko odi pe opolopo alarina laarin Olorun ati eniyan, amofin Paulu ni oro lati ba yin so ” Nitori Olorun kan ni mbe Onilaja kan pelu laarin Olorun ati eniyan, oun paapa eniyan, ani Kristi Jesu” (1 Timoteu 2 :5). Nitori pataki oro yi Paulu gegun fun enikeni pelu oun funrare ti o ba tun waasu ounkoun to yato si ona igbala yi ” Sugbon bi o se awa ni, tabi angeli kan lati orun wa ni o ba waasu ihinrere miran fun yin ju eyiti eyin ti igba  lo je, ki o  di eni ifibu” (Galatia 1 :8). Pataki oun ti Paulu nso fun wa ni wipe Jesu ni eni naa ti Olorun ran si omo eniyan (Heberu 1 :2).  Jesu funra re so pelu idaniloju wipe ” emi ni ONA otito ati iye. Ko si enikeni ti o le wa sodo Baba bikose nipase mi (Johannu 14 :6). Mo fe ki o se akiyesi wipe Jesu so pe oun ni ONA ki si se okan ninu awon ona.

 

O tun le beere wipe ki : lo de ti Jesu nikan fi je ona si odo Olorun ?. Je ki a bere pelu itan Adamu ati Efa. Ki won to da ese, ajosepo to dan moran lo wa laarin Olorun ati eniyan. Ese aigboran ti won da lo si ni ipa lori gbogbo omo eniyan di oni yi (Romu 3:23), Iyapa nla ni ese  da sile laarin Olorun ati eniyan nitoripe Olorun mimo ko le ni ajosepo pelu omo eniyan to ti di elese, ”Sugbon aisedede yin ni o ya yin kuro lodo Olorun yin, ati ese yin ni o pa oju re mo kuro lodo yin, ti oun ki yio fi gbo” (Isiah 59:2). Ni iwon igba ti o si je wipe lai si itaje sile ko le si idariji (Heberu 9:22). Olorun ni lati ran omo re Jesu lati ku dipo emi ati iwo ” nitori Jesu kristi pelu jiya leekan nitori ese wa, olooto fun awon alaisooto ki o le mu wa de odo Olorun” (1 Peteru 3 :18). Nitoripe Jesu Kristi ti san ijiya fun ese wa nipase eje re iyebiye ni ori igi agbelebu, o si so wa po pelu Olorun ” Eyini ni pe Olorun wa ninu Kristi, o nba araye laja sodo ara re, ko si ka irekoja won si won lorun. (2 Korinti 5 :19) Idi niyi ti oruko Jesu nikan fi je ona si odo Olorun. (Efesu 2 :18, 3 :12).

 

Ni afikun si eleyi, Jesu ni awon arimuye ti ko ni afiwe ti o si yato gedegede si awon olori tabi oludasile esin miran. Isotele ti wa nipa ibi re lati bi ogoro odun   siwaju akoko ibi re. Awon iwa re wa ni ailabawon bakanna lo si tun ni aanu ti ko ni afiwe fun omo eniyan. O gba elese la, o wo alaisan san, o fun awon ti ebi npa ni ounje o si le awon emi esu ati aimo jade ninu awon eniyan. Nitori pe esu, iku ati orun apaadi teriba fun oruko re, eyi fun ni agbara lati le ji awon oku dide. O fi agbara re lori iseda han, o ni ki riru omi okun ko dake je, o tun rin lori omi. Iku ati ajinde re je iyalenu.

Egungun awon oludasile esin miran si wa ninu iboji won di akoko yi. Iboji Jesu wa ni ofo! Titi di oni ipa ti Jesu ni lori gbogbo aye si wa sibe bi o tile je wipe akoko perete ti se odun metale logbon nikan ni o gbe ninu aye yi.

 

Koda, awon orisun iroyin kan to yato si Bibeli fi idi awon nkan wonyi mule ni pataki julo T.F. Josephus (37-100 AD) ti o ko nipa igbe aye ati ise iranse Jesu. A ri akosile kan naa ni bi egberun odun meji seyin ni Constantinople. Ninu akosile agbelebu Jesu ko si Romu ninu eyiti o ti nse alaye idi re ti o se fi owo si ikanma agbelebu Jesu. Eyi ga, nitori pe eri pe eri po ni opolopo lati fi idi oro Olorun (Bibeli) mule.

 

Awon oun ti o dara lo ma n sele si eniyan ni igba ti o ba wa si odo Jesu Nitori Jesu nikan ni ONA si odo Olorun. Oun nikan naa ni ona abayo kuro ninu wahala aye re. Oun naa ni Jesu lana, loni ati titi laelae (Heberu 13 :8). Jesu a se ayipada re bi o ti wu ki igbe aye ti o n gbe tele se buru to. Jesu yo fun aye re ni ayo ati idunnu yoo si tun fun o ni ojo ola ti o dara. Gbogbo agbara esu ati awon iranse re bi aje, oso ati beebelo ti di ibaje ni ori re. Jesu yoo fi ibukun re lopolopo fun o yio si ba gbogbo awon aini re pade. Ju gbogbo re lo, yio mu o lo si orun ti o kun fun alafia, ayo ati itunu.

 

Oluka oro mi yi, akoko niyi fun o lati se ipinu Pilatu eni ti o fi owo si ikanmo agbelebu Kristi beere ibeere pataki kan lowo awon Olufisun Jesu ” Kili emi o ha se si Jesu eniti a n pe ni Kristi” (Matteu 27 :22). Eleyi naa si ni ibeere ti Olorun yio beere lowo gbogbo wa ni igba ti a ba pa ipo da wipe ” Ki ni iwo se si ORUKO NAA, ani Oruko Jesu ?” Ti o ba gba Jesu nisinyi, iwo naa yo pelu awon ti won yo lo ayeraye won ni orun rere ninu alafia, itunu, ayo eyi ti ko se fi enu so. Ti o ba si ko, o lo ayeraye re ninu ibanuje, irora, ekun, ipayinkeke to ga lopolopo.

 

Ti o ba fe pe Jesu sinu aye re, gba adura yi pelu gbogbo okan re ” Jesu Olufe, mo gba wipe iwo ni omo Olorun, ko si oruko miran nipase eyi ti a fi le gba eniyan la yato si oruko re. O ku fun ese mi, o si jinde lati gba mi la. Dari gbogbo ese mi ji mi wemimo pelu eje re iyebiye. Wa si inu aye mi ki o si je Oluwa mi tit laelae. O se Jesu nitori o ti gba mi la.

 

Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi

Produced and Distributed  by

GOSET MEDIA MINISTRIES

Leave a Comment

Your email address will not be published.