IWO KO LE DOWO BO

 

“Ko si ohun ti a bo, ti a ki yio si fihan, tabi ti o pamo ti a ki yio mo” (Luku 12:2). Ko si ohun ti eniyan ko le se lati bo ese re mole. O le so ina si odidi ile lati bo ese re mole, pa eniyan tabi pa eniyan lara ki o ma ba si eleri Kankan fun iwa ibaje re ni Iwonba igba ti a ko ba ti ka o mo ibi oran naa. Yoo se oyun lati pa omo ti a ko tii bi lati bo ibasepo ti ko leto mole. Awon eniyan ti won n se eru, ole ipaniyan, ifole ati awon iwa aito miran gba wipe ki awon ku tabi ki won pa eniyan san ju ki asiri won ko tu lo. Gege bi bibeli ti so fun wa, ko si ese naa ti yo wa ni aimo titi.

 

Igbiyanju omo eniyan lati bo ese re mole mu mi ranti itan kan ti o wa ninu awon iwe adura ojoojumo kan, “Our Daily Bread”. Arakunrin kan wa ti ko ni ise meji ju ise fayawo lo. Ni ojo kan ti o n bo lati ibi ise yi pelu oko oju omi to kun bamu fun awon eru ofin, o ri oko oju omi awon ti o n gbogun ti iwa fayawo ti won n le bo leyin. O pe akiyesi awon ti won nba wa oko oju omi yi si ohun ti o ri won si gbiyanju lati salo mo awon wonyi lowo sugbon laipe won ri wipe won o le bo mo won lowo. Nigba ti ko ri awon agbofinro yi nitosi re mo, o pase wipe ki won da gbogbo awon eru ofin yi sinu okun. Logan naa ni won si se bi o ti wi. Nitori wipe ile ti su, awon gbofinro yi ko ri nkan ti onifayawo yi se. Laipe, ina ti o ntan lati ara oko oju omi awon agbofinro to wa leyin onifayawo yi je ki awon onifayawo ri pe eru ti won da si inu okun ko ri. Eyi ya won lenu pupo. Awon eru wonyi to taara tele awon onifayawo yi, eyi ni o si ran awon agbofinro lowo lati tete se awari won. O gbiyanju lati bo eri iwa odaran re mole sugbon awon eru naa ko lati ri sinu okun. Eleyi ni o si se apejuwe oro Olorun to so wipe “Eniti o bo ese re mole ki yio se rere sugbon enikeni ti o jewo ti o si koo sile yio ri anu”(Iwe Owe 28:13) Nje itan yi ran o leti ese ti o gbiyanju lati bo mole ri? O le dabi eni wipe o ti se aseyori sugbon ni ojo kan “Okun” yio ko lati fi owo so owopo pelu re: oke nla yio ko lati ba o wo lu mole. Ile ko si ni gba lati boo mole bee naa ni yio ma tu sita.

 

Gbo mi ara, ese ti o ro pe ko si eniti o mo nipa re yen ko bo rara o. Gbo nkan ti bibeli so “Sugbon ohun gbogbo ni o wa ni ihoho ti a si sipaya fun oju re eniti awa ni iba lo”(Heberu 4:13)

O ko le sa pamo fun  Olorun. O mo, o si n ri ohun gbogbo ti o nse. Ti o ba ko lati doju ko ese re nisisinyi,  laipe  lai jinna ese re yio se awari re yio si fi o se esin.

Olorun korira ese, eniyan si gbodo san idiyele gbogbo ese ti o ba se “Nitori iku ni ere ese, sugbon ebun ofe Olorun ni iye ainipekun ninu Kristi Jesu Oluwa wa” (Romu 6: 23)

Ona abayo kanna ti o wa ni nipa Jesu Kristi. Ti o ba jewo ese re fun Olorun bayi, eje Jesu yo we gbogbo awon ese yi danu, eyi si dara ju ki o bo awon ese yi mole lo. Eje Jesu nikan ni o le bo ese eniyan mole patapata. Nitoripe o we ese wonyi nu, o si we o nu mo patapata lai ni eeri kankan. Olorun fe o si ti setan lati gbo ti iwo naa yo ba la enu re ti o si gbadura. Gbadura bayi nisinsiyi

“Jesu Oluwa, mo gbagbo wipe o ku fun ese mi a si ji o dide fun idalare mi. Dari gbogbo ese mi ji mi ki o si fi eje re iyebiye naa we mi. Wa si inu aye mi ki o si je Oluwa lati oni lo. O se Jesu nitori pr o ti gba mi la. Amin.

 

 

 

Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi

Produced and Distributed  by

GOSET MEDIA MINISTRIES

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *