ITAN IYANU TI KERESIMESI

Itan Keresimesi je itan iyanu ife alailegbe ti Olorun ni si omo eniyan. Jesu gan ni ere idi Keresimesi. Keresimesi je oro ti a mu ninu oro meji ti itumo re je Ajodun awon Kristieni. December 25, 1038AD ni a koko se ajoyo Keresimesi.

 

Itan Keresimesi yi ko kan bere ni ile Isreali bi egberun odun meji seyin. Wiwa Olorun si aye ni aworan eniyan je, afihan oun ti Olorun ti se eto re sile ni Orun ki a to da aye rara (1 Peteru1:18-20) Niwonbi…..  enyin ti mo pe, “a ko fi ohun ti idibaje ra yin pada, bi fadaka tabi wura, kuro ninu iwa asan nyin, ti enyin ti jogun lati odo awon baba nyin; Bi ko se eje iyebiye, bi ti odo-aguntan ti ko li abuku, ti ko si li abawon, ani eje Kristi: Eniti a ti mo tele nitooto saaju ipilese aye, sugbon ti a fihan ni igba ikehin wonyi nitori nyin”. Eyi tumo si wipe bibi, iku ati ajinde Jesu Kristi ti sele ni Orun ki a to da aye. Oun ti o si sele ni Bethlehemu je aworan tabi afihan fun araye oun ti o sele ni Orun.

 

O le ma beere idi ti o fi se pataki fun Jesu lati wa si aye? Ranti Adamu ati Efa ninu ogba Edeni, ibi ti o kun fun opo yanturu ati ajosepo to gun  rege laarin Olorun ati eniyan. Ajosepo to gun rege yi lo baje nigbati Adamu ati Efa se si Olorun ti a si le won kuro ninu ogba Edeni. Ese Adamu yi lo ni ipa lori gbogbo awon omo eniyan. (Romu 3:23) “Gbogbo eniyan li o sa ti se, ti nwon si kuna ogo Olorun” Ese yi lo wa fi ogbun nla si arin Olorun ati eniyan eyiti a gbodo di ki ajosepo miran to tun le wa laarin Olorun ati Eniyan. Idi eleyi lo mu ki Olorun ran omo Re wa si aye nigba Keresimesi (John 3:16) “Nitori Olorun fe araye tobee ge ti o fi Omo bibi re kan soso funni, ki enikeni ti o ba gba gbo ma ba segbe, sugbon ki o le ni iye ainipekun”.

 

Olorun ni lati ran Omo Re ni aworan eniyan eleran ara (Johannu 1:14 )”Oro naa si di ara , oun si n ba wa gbe, t’awa si n wo ogo re, ogo bi ti omo bibi kansoso lati odo Baba wa, t’o kun fun oore – ofe ati otito.”;  (Filippi 2:8) nitoripe ona kanna niyi nipase eyiti eniyan le fi ni oye oun ti Olorun n so. Fun apeere, bawo ni eniyan se le kilo fun opolopo kokoro eera wipe ewu agbara tabi ina ti o le pa won run fe sele si won. Bi o ba pariwo, awon eera ko le gbo. Ona kan na ti o fi le je ki won mo nipa ewu ti o n bo yi ni ki oun na papa di eera. Oun naa gan ti Olorun se ni eyi (Heb1:1-2) “Olorun, ni igba pupo ati li oniruuru ona, ti o ti ipa awon woli ba awon baba soro nigbaani, ni ikehin ojo wonyi o ti ipase omo re ba wa soro eniti o fi se ajogun ohun gbogbo nipase eniti o da awon aye pelu”;

 

Oun ti Jesu wa se laye ni lati se ilaja laarin Olorun ati omo eniyan (2korinti 5:19) “Eyini ni pe, Olorun wa ninu Kristi, O n ba araye laja sodo ara re, ko si ka irekoja won si won lorun O si ti fi oro ilaja le wa lowo!!”. Nje o gbo iroyin ayo ati iyanu yi? Olorun ko ka ese re si o lorun nitoripe o ran omo Re si o ni asiko Keresimesi lati gba iku re ku. (1Peteru 3:18) ” Nitori eyi, a dari gbogbo ese ti a ti se ji wa “Je ki eniyan buburu ko ona re sile, ki elese si ko ironu re sile, si je ki o yi pada si OLUWA, oun o si saanu fun, ati si olorun wa, yio si fi ji li opolopo”  (Isa. 55:7)”. Eyi ni itan iyanu ti Keresimesi.

 

Ore, ibeere pataki kan ti Olorun yo bere lowo eni kokan wa nigba ti a ba de orun ni eyi “ki ni o se nipa Jesu Kristi, ebun iyanu ti Keresimesi”. Nigbati a fe bi Jesu ni Bethlehemu, aye ko si fun Josefu ati Maria ni ile ero. Eyi lo mu ki a bi Jesu ni ibuje eran. Ni o le egberun odun meji leyin eleyi, ogooro eniyan ni ko ni aye fun Jesu ninu aye won, bi o tile je pelu idunnu ni won fi n se ajoyo Keresimesi.

 

Iwo nko? Se aye wa ninu aye re fun Kristi? Ti o ba gba Jesu bayi, wa lo ayeraye re pelu Olorun ni Orun pelu ayo alailegbe ti o kun fun ogo.

 

Ti o ba fe gba Jesu Kristi, ebun iyebiye ti Olorun fun wa ni igba Keresimesi sinu aye re, gba adura yi tokantokan”

Jesu Oluwa, mo gbagbo wipe o ku fun ese mi, o si jinde fun idalare mi. Dari ese mi ji mi ki o si fi Eje Re iyebiye ni we mi mo. Wa si inu aye mi ki o si je, Oluwa nibe titi lailai: Jesu o se nitoripe o ti gba mi la.

 

 

 

Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi

Produced and Distributed  by

GOSET MEDIA MINISTRIES

Leave a Comment

Your email address will not be published.