IRIN AJO AREMABO

 

Jowo  duro je e na fun iseju kan ki o si ronu nipa irin ajo pataki kan ti o ti lo ri tabi igba ti o se se ki o de ilu tuntun tabi orile ede ti o yato si orile ede re. Nigba ti o bere irin ajo yi, se o kan bo si inu oko ofurufu tabi oko ti yio gbe o lo lo ba gbera fun irin ajo naa ?

O daju pe bee ko lo se se.  Ki o to bere irin ajo na, o ti fi owo pamo ki o to lati lo fun irin ajo naa, o o di eru ti o to fun o lati lo ni irin ajo, o o se eto ti o to fun ibi ti o wo si lati sun ati de si pelu gbogbo orisirisi ipalemo ti o ye lati mu ki irin ajo naa ko yori si rere.

 

Oun ti o ya eniyan lenu ti o si se ni laanu nipe opolopo eniyan ma nse ipalemo fun irin ajo inu aye ti o je aremabo ti enikeni ko si le se alaimalo. Opolopo wa la dabi oba kan ninu itan kan eni to fun akinyeye/omugo ti o wa ni afin re ni opa ase re. Kabiyesi so fun omugo yi pe ki o fi opa ase re yi fun enikeni ti o ba ri ti o ya omugo ju u lo. Arakunrin omugo yi gbiyanju titi lati se awari eni ti o go ju ara re lo sugbon gbogbo igbiyanju re ja si pabo nitori ko ri eni ti o go ju oun lo. Laipe leyin akoko yi ni oba ilu yi se aisan to po gidigidi de oju iku. Okunrin omugo yi bere lowo oba iru ipalemo ti o ti se fun irin ajo aremabo eyi ti o fe lo sugbon oba so fun wipe oun ko se ipalemo kankan. Eleyi lo si mu ki okunrin omugo yi fun oba ni opa ti oba f un tele wipe nitooto oba yi go gidigidi ju oun lo. Abi e ko ri eko nla itan yi.

 

Ile aye ti a wa yi je ipalemo fun eyi ti o nbo. Iku re ko ni opin aiye re, irim ajo re yo tun te siwaju ni ayeraye ti ko ni opin. Bi o tile pe laye ti o lo opolopo odun, o  lo ju be lo ni ayeraye. Bi aye eyi ti a wa yi fun wa ni anfani lati yan nkan to wu wa ninu opolopo nkan towa nibe, ayeraye ko ni ju nkan meji lati yan okan ninu re lo eyi si ni orun rere tabi orun apadi. ” Ati opolopo ninu awon ti o sun ninu erupe ile ni yio ji, awon miran si iye ainipekun ati awon miran si itiju ati egan ainipekun” (Daniel 12 :2). Ibasepo ti o wa larin iwo ati Olorun nigba ti o wa laye ni yio so ibi ti wa ti lo ayeraye re. Ti o ba ni ibasepo pelu Olorun ni aye yi nipase omo re Jesu Kristi, o lo ayeraye re pelu Olorun ninu ayo nla ati idunnu ti ko se fi enu so. Ti ko ba si ribe, orun apadi nibi ti iya ati idaamu po ju si ni yio je ipin re.

 

Ki ni idi ti o fi gbodo ni ibasepo pelu Olorun nipase Jesu Kristi ki oba le da orun ? idi re ni wipe gbogbo eda eniyan patapata lo ti wo inu wahala pelu Olorun nitori ese baba nla wa Adamu, Gbogbo eniyan li o sa ti se, ti won si kuna ogo Olorun” (Romu 3 :23). Ijiya fun ese si ni iku (Romu 6 :23). Sugbon Olorun ko ni inu didun si iku elese (Esekieli 33 :11) Nitorina Olorun ran omo re Jesu Kristi lati wa ku ni ipo wa ” Nitori ti Kristi pelu ijiya leekan nitori ese wa, olooto fun awon alaisooto, ki o le mu wa de odo Olorun, eniti a pa ninu ara, sugbon ti a so di aaye ninu Emi” (1 Peteru 3 :18). Iku Jesu Kristi ni o se ilaja laarin awa ati Olorun (2 Korinti 5 :19). Nipase iku Jesu Kristi lori igi agbelebu a pa gbogbo ese wa re patapata nitori wipe laisi itajesile ko si idariji ese (Heberu 9 :22).

 

Orun je ibi ti a ti pese sile fun awon ti won ti palemo fun. Yato si awon irin ajo ile aye yi, o ko nilo lati mu ounkoun dani lo si irinajo aremabo yi ” Nitori a ko mu ohun kan wa si aye, beeni a ko si le mu ohunkohun jade lo” (1 Timoteu 6 :7) Gbogbo oun ti o nilo ni Jesu Kristi ti se ipalemo re fun o ”Ninu ile Baba mi, Opolopo ibugbe li o wa, iba ma se bee, emi iba ti so fun yin. Nitori emi nlo ipese aye sile fun yin (Johannu 14 :2).

IPALEMO ti o nilo lati se ni lati jowo aye re fun Jesu Kristi. Ibeere kan ti yo ko gbogbo wa loju lati odo Olorunn leyin aye yi ni wipe “Ki ni o se nipa ebun omo mi ti mo fi fun o nigba ti o wa ni aye?”

 

Ara Oluka oro yi, o ni lati wa ojutu si ibeere yi ni isinsiyi. Se o fe gba Jesu ni tabi o fe koo ? ipinnu yi wa ni owo re. Ipinnu ti o ba si se ni yio so ibi ti wa ti lo ayeraye re boya ni orun rere ni tabi orun apaadi. Ti o ba fe jowo aye re fun Kristi, dakun fi tokatokan gba adura bayi ” Jesu Oluwa , mo gbagbo wipe iwo ni omo Olorun. O ku o si tun jinde lati gba mi la. Dari gbogbo ese mi ji mi ki o si fi eje re iyebiye ni we mi mo. Wo inu aye mi wa ki o si ma je Oluwa mi lati oni lo. O se ti o gba mi la. Amin’’

 

 

 

Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi

Produced and Distributed  by

GOSET MEDIA MINISTRIES

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *