EKO NLA LATI ARA OKO OJU OMI NLA TI O RI

 

Ni bi ogorun odun seyin (15th April, 1912) isele imu iku ba ni loju omi to ga julo ni agbaye sele. Oko oju omi to tobi kan ti won n pe ni “Titanic” ti o si ni ero to le ni egberun meji (2,224) ninu re ni o ri sinu agbami okun ninu irin ajo re akoko lati Southampton, England lo si New York ni orile ede Amerika ti o si je wipe eniyan egberun kan aabo (1,500) ninu awon to wa ninu oko oju omi naa ni o ku ninu isele naa.

 

“Titanic” tumo si oun ti o tobi ti o si gborin gan. Nitooto, oko oju omi yi tobi pupopupo gan ni. Oko oju omi yi ni aja mewa ti  o si ni gbogbo nkan amayederun ti a le ri ni ile igbafe ti o dara ni agbaye. Won tile ri oko oju omi yi gege bi eyi ti o tobi ju, ti o lagbara ju , ti o si tun wa ni ailewu julo ni gbogbo agbaye. Nitori gbogbo awon nkan arimuye yi lo je ki eni ti o ni oko oju omi naa pe ni oko oju omi ti Olorun paapa ko le je ki o ri. Sugbon Olorun alagbara, eni ti o ti “yan awon oun ailera aye yi lati fi daamu awon ohun ti o lagbara”(1 Korinti 1:27)gba omi didi tabi yinyin laaye lati mu oko oju omi nla naa ri sinu omi. Eko nla ti a koko ko nipa bi oko oju omi nla yi se ri ni wipe oruko Olorun ni owo ju oun ti enikani le ma fi tayin tabi fi se esin. Dipo re, a gbodo ma fi owo ati ola fun(Aisaya 8:13). Orisirisi eniyan lo wa ninu oko oju omi naa, awon olowo, gbajumo, otokun ilu, okunrin, obinrin, omode, ebi ati awon osise inu oko naa. Ki o to di wipe oko oju omi yi bere irin ajo yi, orisirisi nka lo se pataki bi  se olowo ni won tabi talaka, se awon osise wa ni enu ise ni tabi won wa ni isinmi, obirin ni won ni tabi okunrin, won ni eru pupo ni tabi eru won mo ni iwonba. Nigba ti oko oju omi yi ri tan, ko si ikankan ninu awon nkan wonji to se pataki mo. Oun meji pere lo wa se pataki se  won ye ni tabi won ti sonu patapata. Ile ise ti o se oko oju omi yi “White Star Company” gbe atejade oruko jade, ona meji pere ni won pin oruko gbogbo awon ti won wa ninu oko naa si “Awon ti o sonu” tabi “Awon ti o ye”. Eko nla tun ni eyi lati ara isele yi.

 

Ara mi, bi Olorun naa se nwo gbogbo eniyan ni agbaye naa loni niyi, bakanna ni yo se ri won ni aye ti o nbo wa -“O sonu ni tabi o ye”. Ni oju iku, ko si oun kankan ti a ni laye yi ti yo se pataki mo. Wipe o je okunrin, olowo, eniyan dudu tabi funfun, talaka, omowe tabi ope.  Oun ti yo se pataki nigba ti o ba pade  eleda re ni pe se “O sonu ni tabi o ye”. Gbogbo eniyan lo ti sonu sinu ese “Gbogbo wa ti sina kirikiri bi aguntan, olukuluku wa tele ona ara re”(Aisaya 53:6). Sugbon iroyin ayo kan wa fun o “Nitori omo eniyan de lati wa awon ti o nu kiri “ (Luku 19:10). Bibeli tun so wipe “Yio si bi omokunrin kan, JESU ni iwo o pe oruko re, nitori yio gba awon eniyan re la kuro ninu ese won”(Matiu 1:21).

 

Ti o ba fi aye re fun Jesu, a o gba o la kuro lowo ibinu ti o nbo wa, gege bi awon ti o ye ninu oko oju omi TITANIC. A o ko oruko re sinu iwe iye (Ifihan 20:15) o si wa lo wa pelu re ni orun ni ibi ti ayo ailefenuso wa pelu ogo nla. Fun awon elese ti o ti sonu ti won si ko lati fi aye won fun Jesu  ni won o ri titi laelae gege bi awon ti won fi aragba ninu iparun TITANIC. Inu adagun ina ti o njo pelu sulfuri ni ipin awon wonyi titi ayeraye.(Ifihan 20:10-15). Iwo funra re ni o le yan eyi ti o ba wu o. Ti o ba fe fi aye re fun Jesu, gba adura yi pelu gbogbo okan re “Jesu Oluwa, mo gbagbo wipe iwo ni omo Olorun. O ku fun ese mi, o si jinde fun idalare mi. Dari ese mi ji mi ki o si fi eje re iyebiye ni we mi nu mo. Wa si inu aye mi ki o si je Olorun mi lati oni lo. O se Jesu nitori o ti gba mi la. Amin”.

 

Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi

Produced and Distributed  by

GOSET MEDIA MINISTRIES

Leave a Comment

Your email address will not be published.