EJE NI ARA OPO ENU-ONA

Mo fe so itan iku ati iye fun o. Bi o tile je wipe o dabi itan aroso, sugbon otito ni.

Ni ilu kan, awon jagun-jagun fe pa awon eya kan run. Lati se ise ibi yii, olori ogun ilu na pase wipe gbogbo awon eniyan ti o wa ninu ilu naa ni ki a ta eje re sile.

 

Lati ri wipe ko si ile kan ti a ko fi owo kan, awon olote jagunjagun yi bere lati ma fi eje awon ti won ba ti pa si enu opo enu ilekun ile won. Okunrin kan laarin ilu naa gbo nipa eyi. O yara pa ewure kan o si fi eje re si ara opo enu ona ile re. Nigbati awon jagunjagun si ri eje ni enu opo enu ona ile re, won re ile naa koja ni ero wipe awon ti se ise ibi won ninu ile naa. Bi iku se fo awon olugbe ile naa koja niyi.

 

Iru itan yi ni ohun ti osele ninu Bibeli ni egberun meji odun o le die sehin. Iwo gan le ni imo nipa itan yii, Olorun so fun Farao oba Egipti wipe ki o jowo awon omo Israeli lati jade lo lehin ti won se atipo ni ile re fun bi ogbon o le ni irinwo odun. Sugbon o ko jale. Ni asale ojo ti Olorun fe fi owo agbara nla gba won, O pase fun awon omo Israeli ki won ki o pa odo agutan ti ko ni abawon ki won ki o si fi eje re si ara opo enu ona ati aterigba ile won (Eksodu 12:7). Olorun se ileri wipe “Eje yi ni yoo je ami fun yin ninu ile ti e ngbe. Nigbati mo ba si ri ami eje naa, emi yoo re yin koja; ibi naa ki yoo si wa si ori yin lati run yin nigbati mo ba la ile Egipti koja” Eksodu 12:13,23). Ni oru ojo naa, akobi eniyan ati ti eranko ni a pa run (Ekso. 12:29). Ko si okankan ninu omo Israeli ti a fi owo kan nitori ami eje naa.

 

Ohun ti o sele ninu iwe Eksodu je awojiji tabi itokasi ohun ti Olorun yoo se nipase Jesu Kristi ninu majemu titun (Heberu 10:1). Jesu ni odoaguntan alailabawon naa (Eksodu 12:5). Johannu nigbati o nso nipa Jesu so wipe “Woo Odoaguntan Olorun, eni ti o ko ese araiye lo (Johannu 1:29). Jesu ni odoaguntan fun irekoja wa. (1Korinti 5:7)

 

Ese ti Bibeli nso nipa re ni eyi ti a jogun lati odo Adamu. Nipase Adamu ni gbogbo eniyan fi di elese (Rom 3:23) bee si ni iku ni ere se (Romu 6:23). Nitori idi eyi, gbogbo wa ni o ye lati ku; ti o tumo si lilo ayeraye ninu ina orun apadi. Sugbon ife ni Olorun. Ko ni inu didun si iku elese. (Ezekieli 33:11) Nitori naa ni o se ran ayanfe omo re Jesu Kristi lati ku fun ese wa. O ta eje re iyebiye sile fun wa nitoripe laisi itajesile, imukuro ese ko si(Hebrew 9:22). Bi o ba gbagbo ninu Jesu Kristi, bi o ti wu ki ese re po to. Eje Jesu Kristi n we ese nu (1John 1:7).

 

Eje Jesu nsise takuntakun ninu, lode ati titi ayeraye fun awon ti o ba gbaa gbo. O nse iwenumo to daju kuro ninu idalebi ati ero buburu okan.

 

Ni ita awon onigbagbo ni ami eje Jesu ti orun ati orun apadi da mo. Gege bi eje lara opo enu , o ndabobo kuro ewu ati ohun buburu ti o wa ni aye yi. Ju gbogbo re lo, eje yi ni iwe irina si ayeraye (orun) nitori ti Jesu ti ra irapada fun awon onigbagbo nipa eje Re (Hebrew 9:12). Awon ti o ba ko irapada yi yoo lo ayeraye won ni orun apaadi.

 

Ore mi oluka iwe yii, akoko niyi fun o lati se ipinu lati gba Jesu ki o si wa si abe eje naa fun igbala ati abo tabi ki o ko o. Bi o ba fe gba Jesu sinu aye re, jowo gba adura yi “Jesu Oluwa, mo gbagbo pe o ta eje re iyebiye sile fun mi, O ku, o si tun jinde lati gba mi la. Dari ese mi ji mi, ki O si we mi mo pelu eje Re. wa si inu aye mi ki o si maa joba nibe lati isisiyi lo. O seun Jesu fun igbala mi” Amin.

 

 

 

Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi

Produced and Distributed  by

GOSET MEDIA MINISTRIES

Leave a Comment

Your email address will not be published.