DIDAJU ORUN RERE ATI ORUN APAADI

DIDAJU tumo si ki nkan je otito, ojulowo tabi ododo. Ki i se iwoye, igbero tabi iro eni lasan. O je nkan ti a le fi oju ara wa ri ti a si le fi owo kan. Ara mi, ti o ko  b a mo tele, mo gbodo je ki o mo wipe orun rere ati orun apaadi wa ni tooto. Won ki i si se ero inu enikankan. Won wa dajudaju bi ibi ti o ngbe se daju tabi bi iwe ti o nka yi se wa dajudaju ni owo re.

 

Bawo ni mo se mo ?. Mo mo nitoripe Jesu Kristi, eni ti o wa lati orun ri gbogbo re patapata, o so ni opolopo igba ninu Bibeli ti ko si le paro rararara. O so itan awon okunrin meji kan fun wa, Lasaru ati oloro, won gbe ni aye yi. Sugbon nigba ti o ya won ku (Luku 16 :19-31). Lasaru lo si orun rere nigbati oloro lo si orun apaadi. Oloro yi kigbe ni orun apaadi ” Baba Abrahamu saanu fun mi, ki o si ran Lasaru, ki o te orika re bomi, ki o si fi tu mi li ahon, nitori emi njoro ninu owo ina yi” (vs 24) Abrahamu si da lohun wipe ” Omo ranti pe nigba aye re, iwo ti gba rere tire, sugbon nisinsiyi ara ro Lasaru iwo si njoro” (vs 25)

 

Lati inu ibi kika yi, a ri ohun meji, pataki nipa orun rere ati orun apaadi. Akoko orun je ibi itura ati ayo ti ko lopin fun awon OLODODO nikan. Orun ni ibugbe Olorun. O je ibi ailafiwe nibi ti awon olodoodo yio ti bo lowo gbogbo idaamu, wahala, ajalu ati beebelo ni be, ”Olorun yio si nu omije gbogbo nu kuro li oju won, ki yio si si iku mo, tabi ofo, tabi ekun, beeni ki yio si irora mo, nitoripe oun atijo ti koja lo ”(Ifihan 21 :4)”. Ona igboro ilu naa si je kiki wura” (Ifihan 21 :21). Ile itura ti o dara ju ni agbaye ko se se akawe awon ile didara ti o wa ni orun (Johanu 14 :2) ”. Oru ki yio si mo, won ko si ni wa imole fitila tabi oorun, Oluwa Olorun ni yio tan imole fun won” (Ifihan 22 :5) ko si oro naa ti a le fi se apejuwe ni kikun nipa ogo ati itura orun rere.

Ekeji, orun apaadi naa je ibi ti o wa dajudaju fun ijiya awon ALAISODODO ”nibiti kokoro won ki ku, ti ina naa ki si ku” (Marku 9 :46-47). Olorun ko da orun apadi fun eniyan, a da fun esu ati awon angeli re.  (Matteu 25:41) sugbon opolopo eniyan ni won o lo si ibe nitori ainigbagbo ati aimokan. A gbodo je ki o mo wipe ko si agbedemeji, laarin orun rere ati orun apaadi. Ko si ibi iwenumo Kankan ti a ti ma n we ese eniyan nu “ niwon bi a si ti fi lele fun gbogbo eniyan lati ku leekan soso, sugbon leyin eyi idajo” (Heberu 9:27).

 

Ninu aanu re nla, Olorun ti fi aye gba ogoro eniyan kaakiri agbaye lati ni iriri orun rere ati orun apaadi ki won si pada wa si aye lati kilo fun wa. Lara won ni Robert Liardon, ninu akosile re to pe ni “mo ri Orun (www.robberliardon.org) Mary Baxter ”Ifihan orun lati orun wa” (www.mbaxterdivinerevelation.org) (Choo Thomas “Orun ma daju gan ni” choothomas.org) pelu Augustus Chidozie ti o je omo orile ede Najiria ti o ku fun ojo merin ti o si ti wa si aye pada. Ju gbogbo  awon iriri yi lo, ohun agba iyanu kan sele ni bi odun 1989 ni ile Russia, nibi ti gbogbo eniyan mo wipe awon ara ibe ko gba Olorun gbo. Awon onimo sayensi kan ti won je omo ile Russia ni won gbe ile ni Siberia to maili mesan tabi ibuso kilomita merinla. Gbigbona inu iho yi to 2000^F (1,090^c) Ero gbohun gbohun won si gbe ohun ariwo awon eniyan ti won wa ninu iroira ati iya nla ninu iho ile naa, eleyi fi idi akosile ninu Bibeli wipe isale aye yi ni orun apaadi wa (Efesu 4:9-10).

 

Ibeere pataki ti ologbon eniyan yo wa fi iye si ni wipe “Bawo ni mo se le de orun rere? Jesu nikan ni ona si orun rere. O so wipe ” Emi li ona ati otito ati iye, ko si enikeni ti o le wa sodo Baba bikose nipase mi” (Johannu 14 :6). Oun nikan ni ona si orun rere nitori iku re lori agbelebu lo se ilaja laarin awa ati Olorun (2 Korinti 5 :19).  Gbogbo eniyan patapata ni elese nitori ese Adamu, baba nla gbogbo eniyan (Romu 3 :23). Iku si ni ijiya fun ese (Romu 6 :23).  Sugbon Olorun ko ni idunnu si iku elese (Esekiel 33 :11). Nitori naa ni o se ran omo re nikan soso Jesu Kristi lati ku dipo wa (1 Peteru 3 :18) nitori wipe lai si itajesile ko le si idariji ese (Heberu 9 :22). Eje Jesu ti o se iyebiye nikan ni o le so eniyan di OLODODO niwaju Olorun, ki i se ise owo wa ti o dabi akisa elegbin niwaju Olorun (Aisaya 64 :6).

Ara mi, mo pe o loni lati jowo aye re fun Jesu ki o le ba lo ayeraye ni orun rere pelu re. Ti o ba ko ipe yi, o o lo ayeraye re ni inu ina apaadi. Ipinu yi je eyi ti iwo nikan le se fun ara re ; Ti o ba fe fi aye re fun Jesu, jowo gba adura yi tokan tokan ” Jesu Oluwa mo gbagbo wipe iwo nikan ni ona si orun. O ku o si tun jinde lati gba mi la. Dari gbogbo ese mi ji ki o si fi eje re iyebiye we mi nu mo. Wa si  inu aye mi ki o si joba nibe lailai. O se ti o gba okan mi la. Amin.

 

 

 

Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi

Produced and Distributed  by

GOSET MEDIA MINISTRIES

Leave a Comment

Your email address will not be published.