A TI DARI JI O

Niwon igbati aye ba si wa, ohun ajoji ko le se alaisi. Okan ninu iru awon nkan wonyi sele ni ilu Amerika ni odun die sehin. O sele si odomokunrin kan ti won da ejo iku fun lori esun ipaniyan. Ni igbati won nreti ojo iku, won ri oju rere lati odo Aare orile-ede Amerika ni igba naa eniti o pase ki a da awon odaran naa sile ninu agbara ti o ni labe ofin lati saanu fun awon ti won ti gba idajo ijiya ni akoko ti won ba n se ajodun ominira ni odoodun.

 

Sugbon, ohun meji ni o nilati wa ni imuse ki idariji naa to le fi ese mule. Aare gbodo na owo idariji si awon ojiya naa ki awom ojiya naa si setan lati gba idariji yi.

 

Ni ibamu pelu ero ti eniyan, awon yoku fi ayo gba idariji yi, a tu won sile, won si fi ayo darapo mo awon ebi won. Si iyalenu awon eniyan, odomokunrin yi ko lati gba idariji Aare. Niwon igbati ohun meji ti o ni lati sele ki idariji to fi ese mule ko si ni imuse, a pa okunrin odaran yii. Okunrin yi ku, ki ise pe a ko dariji sugbon nitori ti o ko lati gba idariji.

 

Itan yi so fun wa ibasepo ti o wa laarin eniyan ati Olorun. Gbogbo eniyan gege bi awon odaran merin yii lo ti se ti o si ti kuna ogo Olorun (Rom. 3:23). Ese ti a n so nipa re yi, a jogun re lati odo Adamu eniti se orisun gbogbo eda alaaye. Ese Adamu li o fa ese gbogbo eniyan. Bibeli, oro Olorun so wipe “Nitori naa nipase ese enikan, idajo wa si ori gbogbo eniyan eyiti o mu idalebi wa” (Rom. 5:18). Eyi tumo si pe Adamu se, a si jogun ese naa nipase oruko ati eje ti o n lo lati iran kan si omiran. Iwa mimo Olorun nbere wipe elese gbodo jiya nitoripe “iku ni ere ese” (Rom. 6:23). Nitori naa, gbogbo eniyan gege bi awon odaran inu itan yi ni a ti dajo iku fun.

 

Sugbon, Olorun je olufe, oloore ofe ati alaanu ti ko ni inu didun ni iku elese (Eze. 33:11). Gbo bi Olorun se fi eyi han, oro re so wipe “Nitori ti Olorun fe araye to bee ge to fi omo bibi re kan soso fun w a pe enikeni ti o ba gbagbo, ki o ma ba segbe, sugbon ki o le ni iye ainipekun (Johannu 3:16). Niwon igbati o wa ninu aye, Olorun feran re. Ko fe ki o ku. Nitori bee ni o se ran omo re Jesu Kristi lati ku ni ipo re, “Nitori ti Kristi pelu jiya leekan nitori ese wa, olooto fun awon alaisooto ki o le mu wa de odo Olorun” (1Pet. 3:18). Nitori Jesu Kristi san idiyele fun ese wa, nipase eje Re owon, a ti dariji iwo oluka iwe yi, gege bi Aare ile Amerika ni, Olorun ni abe oore ofe n fun o ni idariji fun ese re nipase Jesu Kristi. Sugbon o ni lati gba nipa yiyan ki o to le wa si imuse. Gege bi awon odaran ni, ogunlogo eniyan ni o ti gba ebun yi nipa igbagbo ninu Jesu Kristi, won n yo nisisinyi, won si ti di ominira. Mase ko ebun oore ofe yi bi odomokunrin yi” nitori bawo ni a se le bo bi a ba ko igbala nla (Heb. 2:3). Ijiya fun kiko ebun ofe yi bi oodomokunrin yi ni iku, eyi jasi lilo ayeraye ni ina orun apadi.

 

Tire ni lati yan. N je o fe ko tabi gba ebun naa? Bi o ba fe gba ebun oore ofe idariji yi, jowo fi tokantokan gba adura yi. Jesu Oluwa, mo gbagbo pe O ku fun ese mi, a si ji O dide fun idalare mi. Dari ese mi ji mi ki O si we mi pelu eje iyebiye Re wa sinu aye mi ki O si maa joba lati isisinyi lo. O seun Jesu ti o gba mi la.

 

 

 

Fun alaye kikun, adura ati igbani ni imoran, jowo ri wa tabi pe awon ago ilewo yi

Produced and Distributed  by

GOSET MEDIA MINISTRIES

Leave a Comment

Your email address will not be published.